
Òǹkọrin eré Highlife kan ni ipinlẹ̀ Delta,Arube Otor ló ti gbára dì báyìí láti fẹ ìyàwó mêta ni ọjọ́ kan ṣoṣo.Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ fìdí rẹ múlẹ pé ọjọ́ kọkàndinlógún oṣù kínní ọdún yìí ni ayẹyẹ náà yóò wáyé ní orí pápá ìṣeré Ìjọ Anglican, London Based,Uzere Kingdom, Agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Gúúsù Isoko ní ìpínlẹ̀ Delta.
Nígbà tó ń dáhùn ìbéèrè lórí bí ó ti ṣe pàdé wọn,O ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni òun pàdé wọn ṣùgbọ́n ìfẹ́ tó nípọn ń bẹ láàrin àwọn mẹ́tẹ̀èta àti ìyáálé wọn tó wà nílé.Ó ní òmò kìí bá ìpèlé ìyá rẹ̀ kó sí aṣọ ró ni ọ̀rọ̀ òun nitori bàbá òun náà fẹ́ aya mẹ́ta ní rọ̀gbàrọ̀gbà tí kò sì sí ìyàtọ̀ láàárín ọmọ tìyálé-tiyàwô.Bí irú ewé bẹ́ẹ̀ bá le jẹ́ fún baba òun,ó dájú pé yíò jẹ́ fún òun náà.
Nípa ṣíṣe déédé láàrin àwọn obìnrin náà,Fẹlá Delta ní lákọ lòun wà bí ìbọn téré bá deré ká sí obìnrin láṣọ wò.Kìí sìí rẹ òun rárá.Ọkùnrin ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́ta náà ni a le ní ó fìwà jọ Olóògbé Fẹlá tó ń bá jẹ́ orúkọ.
Ti a kò bá ní gbàgbé, ọdún 1978 ni Félá fi ìyàwó lọ́jọ́ kan ṣoṣo tí orúkọ rẹ sì inú iwe Mérìírí Guinness tí ilé ìròyìn BBC sí ṣe àpèjúwe olóògbé náà gẹ́gẹ́ bíi ẹni tó lè bá obìnrin lò pọ̀ jùlọ lágbàáyé.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
