Kò sí ìdá mẹ́wàá kò sí ọ̀run tí mo sọ l’ọ́jọ́sí;Àsìsọ Ọ̀rọ̀ ni…Adébóyè

Pásítọ̀ Adéjàre Adébóyè

Olórí ìjọ Ìràpadà Ọlọ́run lágbàáyé,(The Redeemed Christiana Church of God)Pásítọ̀ Adéjàre Adébóyè ti sọ lọ́jọ́ ẹtì tó kọjá lọ pé ọ̀rọ̀ kan tí òun ti sọ níjọ́hun pé ẹni yòówù tí kò bá dá ìdá mẹ́wàá yóò pàdánù ìjọba ọ̀run kò rí bẹ́ẹ̀ àti pé ọ̀rọ̀ náà kò sí ní inú bíbélì.

Àgbà ọ̀jẹ̀ Olùṣọ́ àgùtàn náà ní ahọ́n ló gbé òun tí òun fi sọ bẹ́ẹ̀ àti pé kò sí ẹni tó kọjá àsìṣe.

Adébóyè fojú ọ̀rọ̀ yìí léde nígbà tí ó ń bá àwon ọ̀dọ́ ìjọ náà sọ̀rọ̀ níbi ìpàgọ́ wọn ọlọ́dọọdún ti ọdún yìí tó wáyé ní olú ilé ìjọ náà tó wà ní òpópónà Èkó sí Ìbàdàn.

Ìríjú Ọlọ́run náà ni àṣìṣè ńlá gbáà ni ọ̀rọ̀ náà.Ṣé a máa ń sì wí ṣùgbọ́n a kìí tẹnu mọ ni. Adébóyè ní “Mo fi àsìkò yìí tọrọ àforíjìn lórí ọ̀rọ̀ tí mo sọ nijọ́sí pé ‘Ẹni tí kò bá san ìdá mẹ́wàá kò ní wọ ìjọba ọ̀run’ Ọ̀rọ̀ náà kò sí ní inú bíbélì rárá,àròsọ pátápátá ni.Ọ̀nà ti a fi lè wọ ìjọba Ọlọrun ní kí á wà ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn,ká sì gba Ọlọ́run gbọ́”

Adébóyè tẹ̀ síwájú pé “Gẹ́gẹ́ bíi onímọ̀ ijinlẹ Sáyẹ́ǹsì, ìgbàgbọ́ ni pé ọ̀nà sòòṣé nìkàn ni iná máa ń tọ̀; ṣùgbọ́n ìtèsíwájú nípa iṣẹ́ ìwádìí ti fi léde bayii pé iná a máa tọ òpópó ìjì náà. Ọ̀nà oko a sì máa yí padà ká tó wá sọ pé ọ̀rọ̀ ẹnu”

Ó wá lo àkókò náà láti tọrọ gááfárà lọ́wọ́ gbogbo ènìyàn látàrí jágbá-n-rúju tí ọ̀rọ̀ náà ti dá sílẹ̀.

1 thought on “Kò sí ìdá mẹ́wàá kò sí ọ̀run tí mo sọ l’ọ́jọ́sí;Àsìsọ Ọ̀rọ̀ ni…Adébóyè”

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×