Ìròyìn Ní Yàjóyàjó:Délé Fárótìmí:Amòfin Tó Ń jà fún Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Gba Òmìnira

Àjàfẹ́tọ̀ọ́ọmọnìyàn nnì, tíí tún ṣe Agbẹjọ́rò, Délé Fárótìmí ti gba ìdáǹdè láti ọ̀dọ̀ ilé ẹjọ́ Májísíréètì kan ní ìlú Adó-Èkìtì. Ọgbọ́n mílíọ̀nù náírà ni ojì owó béèlì tí wọ́n ta á, eleyii tí Onídùró rẹ̀ fi gba ìdáǹdè fún ùn.

Fárótìmí ló fi ẹ̀ṣùn kan Amòfin Àgbà,Afẹ́ Babalọlá pé bí ẹni ra ẹ̀kọ òhun àkàrà ni ó ṣe máa ń ra ìdájọ́ lọ́wọ́ àwọn Adájọ́.ati pé ètò ìdájọ́ ní ilẹ Nàìjíríà ti di Kátà-kárà, ẹní tó bá sì lówó lọ́wọ́ ni ètò ìdájọ́ ń gbè fún.

Ìwé náà ló fa bí àwọn agbófinró ṣe mú un tí wọ́n sì gbé e lọ sí ilé ẹjọ́ nibi ti wọn ti ní kó máa gba atégùn lọ́gbà atóríṣe kí wọ́n tó gba béèlì rẹ̀ lóni-ín.

Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn ń bọ̀ lọ́nà…..

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×