
Bí ọba kan kò bá kú,ọba kan kò jẹ.Ìjí kò sí ní jà titi kó da omí inú àgbọn nù.Gbogbo àwọn àsamọ̀ yìí ń tọ́ka sí pé mìmì kan kò ní Mamud Yakubu tíì ṣe alága àjọ INEC ní Nàìjíríà titi ti yóò fí ló sáà rẹ̀ tán.
Àwọn olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún Ààrẹ Tinúbú lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn ìgbàlódé, Ọ̀gbẹ́ni Otega Ogra àti olùrànlọ́wọ́ Ààrẹ mìíràn, Ọ̀gbẹ́ni Daniel Bwala ní wọ́n ti ṣẹ̀ ìròyìn tó hùyẹ́ tó ń fò káàkiri pé Ààrẹ Tinúbú ti yọ Yakubu nípò láti yan elomiran ní igbaradi fún ètò ìdìbò gbogbogbo ọdún 2027
Nínú ìpàdé oniroyin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ti àwọn méjèèjì ṣe ni ilu Abuja ni wọ́n ti fí ojú ọ̀rọ̀ yìí léde.Wọ́n ni àwọn oníbàjẹ́ ènìyàn kan tí wọ́n kò fẹ́ nǹkan rere ni wọ́n ń pin ọ̀rọ̀ náà ká.
Wón wá rọ àwọn ọmọ Naijiria láti má ṣe gba sùnmọ̀mí náà gbọ́.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
