
Lẹ́hìn Pọ̀pọ̀ṣìnṣìn ọdún Kérésìmesì Àti Òdún tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kógbá sílé,ikọ̀ ìròyìn Naija notes tẹ ọkọ̀ létí yí ọjà ká láti mọ ibi tí nǹkan gbé dé dúró lórí owó ohun tí ẹnu ń jẹ.
Ìwádìí sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé nígbà tí àwọn owó ọjà kọ̀ọ̀kan sì wọ́n gógó síbẹ̀, àwọn miiran ti ń bọ́ aṣọ ìgbéraga kúrò ní ọrùn kóówá wọn. Àbọ̀ ìwádìí wa rèé:
Àpò Ìrẹsì kan ní báyìí tó Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rin sí ẹgbẹ̀rùn lọ́nà ọgọ́rùn-ún náírà.Kobíowú/rọ́bà kan tó Ẹgbẹ̀rún mẹ́ta sí Ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó dín ọ̀ọ́dúnrún náírà.
Láàrin ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ sí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta naira ni kobíowú/Rọ́bà erèé kan.Olòyin ló wọ́n jù.
Èlé iṣu kan bẹ̀rẹ̀ láti orí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún.Gàrí ní tirẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti ẹgbẹ̀rin sí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ náìrà fún kobíowú/Rọ́bà kan Èlùbọ́ àti semo vita nìkàn ni wón kò ì tíì wálẹ̀.
Bí àwọn ọjà ohun tí ẹnu ń jẹ ṣe wọ́n owó sí lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí ni yen.Eledumare yóò máa pèsè fún àìní wa oo.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
