
Ìrìnàjò ìkẹyìn fún Diákónì Samson Òláníyì Adébáyọ̀ George ti bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìṣìn ninu ijọ Oore-ọ̀fẹ́ Baptist Church, Ilẹ̀-Olújìí lánà-án Sunday.
Nínú ìwáásù rẹ̀, Àlùfáà Philip Adékúnlé Ọmọ́kanyè rọ àwọn Onígbàgbọ káàkiri àgbáyé láti gbà pé èrè kankan kò sí fún wọn l’ayé yìí bí-kò-ṣe ìjọba ọ̀run.Ó ní bí wón bá ti kọ ọ̀rọ̀ yìí sí wàláà oókan àyà wọn, kò ni nira fún wọn láti mú ayé yìí dẹngbẹrẹ tí wọ́n yóò sì máa wo Jésù gẹ́gẹ́ bíi àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ wọn.

Ó wá ṣe àpèjúwe olóògbé bíi Onìgbàgbọ́ tòótọ́ tí kò fi wèrè pe Ọlọ́run titi tó fi sí ilẹ̀ wa.
Àna ni Bàbá George jẹ́ sí Ògbóhùntarìgì Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ nni;Adébáyọ̀ Ọ̀walà.Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ANBROAD bíi Bisi Ajíbóyè Ṣọ́gigùn, Ṣọlá Gbàyíṣemóre, Oyè Oyèdọ̀tun,Àjàrí Èkìtì,Àkèo bài-yèi àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ ló péjú-pésẹ̀ síbi ìṣìn ìkẹyìn náà.

Ètò ìsìnkú náà ń tẹ̀ síwájú lónìí ní ìlú Òtu ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ nibi ti baba yóò ti wọ káà ilẹ̀ sùn.

Ọ̀pọ̀ Ọmọ àti ọmọ-ọmọ ló gbẹ̀yin bàbá onínúure náà.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
