Ipò Àgbà pè fún Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ìfarajìn…Ọ̀gá Ọlọ́pàá

Ọ̀gá Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Oǹdó,Àbáyọ̀mí Peter Ọ̀ládipúpọ̀ ti rọ àwọn ọ̀gá ọlọ́pàá tí wọ́n sẹ̀sẹ̀ gba ìgbéga ní ìpínlẹ̀ náà kí wọ́n rí ipò tuntun náà gẹ́gẹ́ bíi àlékún ìfarajin nitorí bí orí bá ṣe tóbi tó ló ṣe ń fọ́ olórí.

Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá náà fojú ọ̀rọ̀ yìí léde níbi ayẹyẹ ìgbéga tí wọ́n ṣe fún àwọn ènìyàn náà nílùú Àkúrẹ́.

Kọmísánà ọlọ́pàá náà ní ohun tó mú ìgbéga bá àwọn ènìyàn náà ni bi won ṣe jára ń iṣẹ́ sí.Ó wá rí wón kí wọn má ṣe jẹ kí ó rẹ̀ wón nínú akitiyan wọn lati mú kí ìwà ọ̀daràn tí wọn ń gbógun tì dì èèwò nílé Naijiria.

Lára àwọn tí wọ́n gba ìgbéga ní: John Agwuoye tó dì DSP láti ipò ACP àti Kàbírù Akínróyè tóun náà di ACP.

Àwọn yòókù ní àwọn SP mẹ́rìndínlógún tó gba Ìgbéga sí ipò CSP.Dírẹ̀ lára wọn ni àwọn Ọ̀gá Ọlọ́pàá Ìjọ̀kà,Òkè-igbó,Bọ́lọ́rundúró,Òtú..abbl.

Nígbà tí ó ń fèsì lórúkọ àwọn oloriiré náà,DSP John Agwuoye dúpẹ́ lọ́wọ́ Kọmísánà, Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá nílẹ̀ wa àti Àjọ tó ń mojú ọ̀rọ̀ Ọlọ́pàá nílẹ̀ wa.

Ó wá jẹ̀jè àlékún ìfarajin òun àti àwon àkẹgbè rẹ̀.

Ọ̀gọ̀ọ̀ró awọn eniyan ló péjú-pésẹ̀ síbi ayẹyẹ ìgbéga náà.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×