Ìpínlẹ̀ Oǹdó Ṣe Ìfilọ́lẹ̀ ìgbìmọ̀ Ìgbìmọ̀ Ayẹyẹ Ìrántí Àwọn Ọmọ Olóógun tó Sún lójú ìjà ti ọdún 2025

Díákónì Lọlá Fágbèmí

Alákóso fún ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ àwọn obìnrin ní ìpínlè Oǹdó, Díákónì Lọlá Fágbèmí ti ṣe Ìfilọ́lẹ̀ ìgbìmọ̀ tó máa wà ní ìgbánnu ètò gbogbo tó jẹ mọ́ ayẹyẹ ìrántí àwọn ọmọ olóógun ti ọdún 2025.Àná ọjọ́ kẹẹẹ́dọ́gbọ̀n oṣù kọkànlá ọdún 2024 ni Kọmísánnà ṣe ìfilọ́lẹ̀ igbimo náà ní Gbọ̀ngán ńlá kan ní ọọ́fíìsì rẹ̀.

Nígbà tó ń jẹ́ iṣẹ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ Oǹdó, Họnọrébù Lucky Orímisàn Aiyédàtiwa níbi ayẹyẹ ọ̀hún, Fágbèmí ní ojúṣe ìjọba àti àwọn ará ìlú ní láti rí i pé àwon àbọ̀dé olóógun àti àwọn Mọ̀lẹ́bí wọn ń gbé ìgbé ayé tó dára. Ó wá jẹ́jẹ̀ẹ́ pé ìjọba ìpínlẹ̀ Oǹdó kò ní tẹ̀tì nínú ojúṣe rẹ̀ láti pèsè ìrànwọ́ owó fún àwọn opó àti Mọ̀lẹ́bí àwọn tó fí ẹ̀mí wọn rúbọ nítorí kí Naijiria le wá ní ìrẹ́pọ̀ .

Ó tẹ̀ síwájú pé ìjọba ìpínlẹ̀ Oǹdó ti pinnu lati ṣe ayẹyẹ ti ọdún yìí ní ìlànà ọ̀tọ̀ láti fi èmi ìmoore hàn sí àwọn òpómúléró orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ó wá pàṣẹ fún gbogbo àwọn ìjọba ìbílẹ̀  ní ìpínlẹ̀ yìí láti ríi dájú pé ọ̀wọ̀n àwọn ọmọ olóógun tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ kóówá wọn ló wà ní ipò tó dára saájú ojọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kínní ọdún 2025 tí ayẹyẹ náà yóò wáyé.

Ó wà ṣe ìbúra fún àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ ọ̀hún pẹ̀lú èròngbà láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lẹ́yẹ-ò-sọkà nípa ṣíṣe àbẹwò sí gbogbo àwọn ọ̀wọ̀n olóógun tó wà láwọn ìjọba ìbílẹ̀ pátápátá. Tí wọ́n ó sì ṣe ìfilọ́lẹ̀ ẹḿbúlẹ́ẹ̀mù títà ni ojọ́ Kejìlá oṣù tó ń bọ̀

Lára àwọn ọmọ igbimo náà ni olórí àwọn ajagunfẹ̀hìntì ní ìpínlẹ̀ Oǹdó, Olórí àwọn ọmọ olóógun ọ̀wọ́n kejilélọ́gbọ̀n tó wà ní ìpínlẹ̀ Oǹdó, Kọmísánnà awọn ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ yìí,akọ̀wé àgbà ajókòómádìde ti ilé iṣẹ tó ń mójú tó ọrọ àwọn obìnrin, àwọn lọ́gàálọ́gàá ẹka tó ń mójú tó ìdàgbàsókè agbègbè ní gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ méjèèjìdínlógún yíká ipinle Oǹdó àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.

Bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1970 ti ogun abẹ́lé ilẹ̀ yii parí,ni ìjọba àpapọ̀ ti ń ṣe iranti àwọn ọmọ olóógun tó ṣùn lójú ìjà ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kínní ọdọọdún.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×