

Ìjàm̀bá iná àjóòkú kan tó ṣẹlẹ̀ lóru àná mọ́jú òní tí gba aṣọ lára ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn oníṣòwò inú ọjà náà látàrí bí ó ti sọ àwọn ọjà tótó ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ mílíọ̀nù náírà di eérú.Ikọ̀ ìròyìn Naija notes gán-ánní ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ìròyìn kò sì tó àfojúbà ni.
Ọ̀kan lára àwọn tó fara kááṣá ìṣẹ̀lẹ̀ náà,tii tún ṣe èèkàn kan gbòógì nínú ọjà náà,Ọmọọbabìnrin (ìyáàfin )Ẹnúfọ̀ sàlàyé pé alẹ́ àná ni òun ṣẹ̀ṣẹ̀ já ọjà tuntun sí soobu òun tí gbogbo rẹ sì ti di eérú bayii O wá rọ ìjọba ìpínlẹ̀ Oǹdó lábẹ́ ìsàkóso Gómìnà Lucky Orímisàn Aiyédàtiwa lati jòwó jàre ràn wọ́n lọ́wọ́.
Oníṣòwò miiran tó tún bá oníròyìn wa sọ̀rọ̀,bi-o-tilẹ̀-jẹ́-pé ẹkún kò gbàá láàyè láti sòrò tán dì ẹ̀bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ru iná tó lágbára ti àwọn àjọ BEDC mú wá lórí.
Nígbà tí ó ni fèsì, Olórí ìgbìmò aṣàkóso ìjọba ìbílẹ̀ Òkìtìpupa,Ọmọọba Ọjọmọ ;Ẹni tó sójú alága ìjọba ìbílẹ̀ Òkìtìpupa, Họnọrébù Akínrìnwá níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà pàrọwà fún àwọn ìyálọ́jà àti Bàbálájé pé kí wọ́n gbà pé òfò ènìyàn kò ní ṣe ẹlòmíràn àti pé ẹní tí wọn kò bá kí ní Ọlọ́run yóò fi òfò ra ẹ̀mí, kò lè ní ẹ̀mí gígùn.
Ọjọmọ wá gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kí ó fi òfò ra ẹ̀mí wọn kí Ó sì tu àwọn ènìyàn náà nínú nípa gbígbé Olùrànlọ́wọ́ dìde sí àwọn ènìyàn ọ̀hún ní kíákíá.
Olórí ìgbìmọ̀ aṣàkóso ìjọba ìbílẹ̀ Òkìtìpupa wá jẹ́jẹ̀ẹ́ ìrànlọ́wọ́ ìjọba ìbílẹ̀ Òkìtìpupa ní pàtó àti ipinlẹ̀ Oǹdó fún wọn.Ó ní lẹ́yẹ-ò sòkà ti awọn ti gbọ́ nípa ìṣẹlẹ náà ni àwọn ti fi ọ̀rọ̀ náà tó ìjọba ìpínlẹ̀ Oǹdó létí. Nǹkan bíi agogo kan òru àná ni a gbó pé iná ti ẹnìkan kò mọ orísun rẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ tí gbogbo ipá tí wọ́n sà láti pa iná náà já sí pàbó kódà, gbogbo nọḿbà ti ó wòlé sí ọ̀dọ̀ àwọn àjọ Panápaná ló kù tí kò lọ ní àsìkò náà.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
