Ìlú Òkè-Ọrọ̀ Àkókó Ṣe Ọdún Ìjẹṣu

Ọ̀kan pàtàkì lára ọdún ìbílẹ̀ tó gbajúgbajà ní ọdún Ìjẹṣu jẹ́ ní ilẹ Yorùbá.Òhun sì ní kọ́kọ́rọ́ tó sí ilẹ̀kùn iṣu òhun iyán jíjẹ fún tèwè tàgbà ìlú nitori èèwọ̀ ni fún ẹnikẹ́ni láti fi ègbodò banu bí Kábíyèsí kò bá tíì jẹ iṣu.

Ẹ̀rín ò yàtọ̀ tó fi dé ìlú Òyìnbó nítorí bí wón ti ń ṣe Láké ní wọn ń ṣe Lókò,bákán náà sì ni wọ́n ṣe ní ìlú Òkè-Ọrọ̀ Àkókò lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí níbi tí tarúgbótòyikì omọ ìlú náà ti péjọ̀ sí ilé ọba Ọláńrewájú Adéyẹmí tí gbogbo onípòjipò ènìyàn bíi àwọn Olóyè,tọkùnrin-tobìnrin,ọmọdé,àgbà,ọ̀dọ́ àtàwọn àlejò ti rin irin afẹ́ lọ sí ààrin gbùngbùn ọjà ilú náà níbí tí Kábíyèsí ti léwájú ètùtù ọdún eléyìí tí Ọ̀dọ̀fin Òyì Òkè-Ọrọ̀ , Olóyè Paul Òjó Adéyẹmí darí

Bí aro ti ń sọ,ní àgẹ̀rẹ̀ ń ṣẹ̀,ọlọ́dẹ kó sí ijó kódà,òkìtì pọnlápọnlá làwọn eléégún fi ń já bàtá.Ààfin ìlú náà tó ti wà láti ọdún 1872 ní wọ́n sì fi àdàgbá ìrìn afẹ́ náà rọ̀ sí.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, Kábíyèsí Ọláńrewájú Adéyẹmí dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ibi tó ran ìlú náà lọ́wọ́ dé. Ó sì dúpẹ́ fún àtìlẹ́yìn aláìlẹ́gbẹ́ tí àwọn ọmọ ìlú náà fún un pàápàá jùlọ lásìkò kọ̀bàòle ọ̀rọ̀ kóòtù.

Lẹ́yìn èyí ló lu Gómìnà ìpínlẹ̀ Oǹdó, Họbọrébù Lucky Orímisàn Aiyédàtiwa lọ́gọ ẹnu fún ìpinnu rẹ̀ láti fún ìlú Òkè-Ọrọ̀ Àkókó lómìnira lọ́jọ́ kẹta oṣù keje ọdún 2023.

Nínú ọ̀rọ̀ kóówá wọn,Ìyálájé Òkè-Ọrọ̀, Olóyè Àìná aya Balógun,ìyálọ́jà, Olóyè Ọpẹ́yẹmí àyà Attah,Baálẹ̀ Gàníyù Ibraheem, Mohammed Musa Saheed tí wọ́n mọ̀ sí Sindodo,Olorigba ti ìlekeere ti Òkè-Ọrọ̀, Olórí Ọ̀dọ́, Suleiman Sikiru,Òpóóró ti Òkè-Ọrọ̀, Adéyẹmí Kọ́láwọlé,Alukoro àwọn ọmọ ìlú Òkè-Ọrọ̀ ní ìlú Àkúrẹ́; gbogbo wọn dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún dídá ẹ̀mí wọn sí.Wọ́n gbàdúrà fún ìtẹ̀síwájú ìlú Òkè-Ọrọ̀ Àkókò

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×