
Lójijì ní ìròyìn tàn kiri ní kùtùkùtù òwúrò òní pé ògbóhùntarigì olóṣèlú nnì Doyin Òkúpè di olóògbé.
Ó ti tó ọjọ́ mẹ́tà tí ó ti ń wàyá ìjà pẹ̀lú àrùn jẹjẹrẹ; ìgbàgbọ sì ni pé àisàn náà ló gba ẹ̀mí rẹ̀.
Ọmọ bíbí ìlú Ìpẹ́ru ni ìpínlẹ̀ Ògùn ni Òkúpè.Ẹni ọdún méjìléláàádọ́rin ní í ṣe.Ó ti fìgbà kan rí jẹ́ Olùbádámọ̀ràn pàtàkì sí Ààrẹ Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́,Atiku Abubakar àti olùdarí àgbà fún ètò ìpolongo Peter Obi nígbà tó ń díje fún ipò Ààrẹ lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party ní ọdún 2023.
Àtẹ̀jáde kan ti ó ti ọwọ́ àwọn Mọ̀lẹ́bí olóògbé jáde ló fi ìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀.Ki Olúwa kó tẹ́ ẹ sí afẹ́fẹ́ rere.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
