
Àjọ eleto idibo nipinle Ondo tí a mọ̀ sí ODIEC ti bèrè itanijí ohun ìlánilọ́yẹ̀ fún àwọn olóṣèlú ní ìgbáradì fún ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ ti yóò wáyé yíká ìjọba ìbílẹ̀ méjèèjìdínlógún tó wà ní ìpínlẹ̀ Oǹdó ní inú oṣù kìíní ọdún 2025.
Alága àjọ náà ní ìpínlẹ̀ Oǹdó, Ọ̀mọ̀wé Joseph Àrẹ̀mọ sọ pàtàkì tí tẹ̀lé ìlànà àti àlàkalẹ̀ ètò ìdìbò fún àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú gbogbo.. Gégé bí ó ṣe wí, àtúnṣe yóò bá ìdìbò kò-mẹsẹ̀-ó-yọ tí a mọ̀ sí primary election láàrin àwon ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ pàápàá jùlọ nibi tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn ti kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀ lọ sí ibòmíràn.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, kọmísánnà kan nílé iṣẹ́ náà, ọ̀gbẹ́ni Délé Akínyẹ̀lúrẹ̀ fi dá àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú lójú pé arọ̀wá kan kìí wẹ̀yìn ni àjọ náà yóò fi ètò ìdìbò ọdún 2025 tó ń bọ̀ náà ṣe àti pé àwọn kò ní fá orí apá kan dákan sí nínú gbogbo àlàkalẹ̀ ètò wọn.
Ó wá rọ àwọn Olóṣèlú láti Jáwé akìwọwọ fún gbogbo àwọn olólùfẹ́ wọn láti mú àlàáfíà ní pàtàkì.
Ẹgbẹ́ òṣèlú tó tó merindinlogun lo péjú-pésẹ̀ síbi ìpàde àpérò náà.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
