Ìjọba Àpapọ̀ ti ṣetán láti san Àjẹ́ẹ́lẹ̀ owó sọ̀gbàdẹ̀rọ̀ fún Àwọn Òṣìṣẹ́ Rẹ̀

Ìjọba Àpapọ̀ ti ṣetán báyìí láti san Àjẹ́ẹ́lẹ̀ owó sọ̀gbàdẹ̀rọ̀ oṣù márùn-ún tó jẹ àwọn Òṣìṣẹ́ rẹ̀ yíká orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Àtẹ̀jáde kan láti ọọ́fíìsì olùṣírò owó àgbà nile wa tó gba ọ̀dọ̀ alukoro àgbà ní ọọ́fíìsì náà  Bawa Mokwa jáde ló fi ọ̀rọ̀ náà léde.

Gẹ́gẹ́ bó ti wí, oṣù kẹrin yìí, ní kété tí wọ́n bá ti san owó oṣù kẹrin tán ni àláàtìe ẹgbẹ̀rún márùndínlógójì náà yóò máa dún titi tí yóò fi di ìparí oṣù kẹjọ ọdún yìí.

Ó wá jẹ́jẹ̀ẹ́ pé ìjọba àpapọ̀ kò ní fi ìgbáyé-gbádùn àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ játàáà.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×