
Mínísítà fún ọ̀rọ̀ abẹ́lé nílẹ̀ wa,Olúbùnmi Túnjí Òjó ti kéde ọjọ́ ajé ọjọ́ kìíní àti ọjọ́ ìṣẹ́gun ọjọ́ keji oṣù kẹrin ọdún yìí gẹ́gẹ́ bíi ọjọ́ ìsinmi lẹ́nu ìṣẹ́ láti le fi ṣe pọ̀pọ̀ṣìnṣìn ọdún ìtúnu ààwẹ̀ ti ọdún yìí.
Bí a kò bá gbàgbé, ọjọ́ kìíní oṣù kẹta ọdún yìí ni àwọn mùsùlùmí káàkiri àgbáyé bẹ̀rẹ̀ ààwẹ̀ Ramadan ti ọdún yìí tí ìrètí sì wà pé yóò tẹnu bọ epo ní òpin ọ̀ṣẹ̀ yìí.

Ọ̀gbẹ́ni Túnjí Òjó nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ wá kí àwọn Mùsùlùmí yíká ilẹ̀ Nàìjíríà kú ayẹyẹ ọdún pẹ̀lú àdúrà pé ẹ̀mí wọn yóò ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún láyé.
Bákan náà ló rọ̀ wọ́n láti tẹ̀ síwájú láti máa yàgò fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti yàgò fún nínú osù alápọ̀nlé náà.Ó rọ̀ wọ́n síwájú síi láti máa gbàdúrà fún Nàìjíríà kí wọ́n sì máa wà ni àlàáfíà pẹ̀lú ẹ̀dá gbogbo.
Ìrètí wà pé iṣẹ́ yóò bẹ̀rẹ̀ káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ́jọ́ kẹrin lẹ́yìn pọ̀pọ̀ṣìnṣìn ọdún ìtúnu ààwẹ̀ náà.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
