Ìgbẹ́jọ́ Nnamdi Kanu bẹ̀rẹ̀ L’ákọ̀tun Ńí Ìlú Abuja

Ọ ní òun kò jẹ̀bi ẹ̀ṣùn ìgbésùnmọ̀mí…

Agbẹjọ́rò tuntun ,Kanu Agabi ló ń gbẹnusọ fún un báyìí..

Adájọ́ Binta iyako dìde lórí àga ìdájọ́ fún Adájọ́ James Ọmọ́tọ́ṣọ̀..

Ajìjàgbara tó ń jà fún òmìnira ilẹ̀ Biafra nnì, Nnamdi Kanu ló tí sọ yanya pé òun kìí ṣe onísùnmọ̀mí.Ó ní àṣà kò jọ Kúnnúgbá,bẹ́ẹ̀ ni Àwòdì kò jọ ejò afàyàfà; Ajàfún-òmìnira yàtọ̀ gédégédé sí oníjàádì àti Agbésùnmọ̀mí.Ó ní ẹ̀tọ́ àwọn ẹ̀yà igbo àti ìdásílẹ̀ Orílẹ̀ èdè olómìnira Biafra ni òun ń jà fún.

Ọjọ́ Jimoh ló fi ojú ọ̀rọ̀ yìí léde nígbà tí ìgbẹ́jọ́ ẹ̀ṣùn oníga púpọ̀ tí wọ́n fi kàn án tún gbéra sọ lákọ̀tun ní ìlú Abuja.

Bí a kò bá ní gbàgbé, Adájọ́ Binta iyako ló ń ṣe ẹjọ́ náà tẹ́lẹ̀ kó tó di pé Adájọ́ James Ọmọ́tọ́ṣọ̀ tẹ́wọ́ gba ẹjọ́ náà.Àná Jimoh sì ní igbà àkọ́kọ́ tí yóò bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ náà.Kanu Agabi tíì ṣe Agbẹjọ́rò àgbà àti Mínísítà fún ètò ìdájọ́ ní orílẹ̀-èdè wa tẹ́lẹ̀ rí ni Àgbẹjọ́rọ rè tuntun nígbà tí Amòfin Awomàálọ̀ ń ṣojú ìjọba.

Kanu Agabi kọ́kọ́ tọrọ̀ áforíjìn lọ́wọ́ Adájọ́ jyako àti hAwomàálọ̀ fún ọ̀rọ̀ Alùfàsà tí Kanu ti sọ sí wọ́n pàápàá jùlọ nígbà tí ó ń bẹ̀bẹ̀ fún Adájọ́ mìíràn.

Nígbà tó ń fèsì, Adájọ Iyako ní òun kò bínú nítorí ẹni tí a bá nà ni ara ń ta.Ní ti Awómàálọ̀,ó ní oó di dandan ki Kanu kanra nitori ẹlẹ́ran ara ni òun náà àti pé ẹni tí ìyà òmìnira bá ń jẹ kò lè ní ọ̀rọ̀ rere lẹ́nu nítorí ẹni tí ebi ń pa kò gbọdọ ìwàásù.

Láti kin ẹ̀bẹ̀ tí wọ́n ń bẹ kóówá lẹ́yìn,Adájọ́ Ọmọ́tọ́ṣọ̀ ṣe àlàyé pé ọdún 2015 nígbà tí Kanu jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàdínláàádọ́ta ni ẹjọ́ náà ti bẹ̀rẹ̀;ní bāyii,Kanu ti di ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta .Èyi túmọ̀ sí pé ìgbẹ́jọ́ náà ti bẹ̀rẹ̀ láti ọdún mẹ́wàá ṣẹ́yìn.Nígbà tí a bá wà fi ogún ọdún pilẹ̀ wèrè,ìgbà wo gan-an ni a tó fi bu igi jẹ? Ó wá bẹ Adájọ́ Nyako àti Agbẹjọ́rò àgbà Awómàálọ̀ kí wọ́n fi ọwọ́ wọ́nú.

Adájọ́ Ọmọ́tọ́ṣọ̀ wàá sún ìgbẹ́jọ́ sí ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹrin, ọjọ́ Kejì àti ìkẹta oṣù karùn-ún ọdún yìí .

Orilẹ èdè Kenya ni wọ́n ti fi páńpẹ́ ọba mú Nnamdi Kanu tí wọ́n sì wà á wá sí ilé láti wá jẹ́jọ́ lórí ẹ̀ṣùn tó ní ṣe pẹ̀lú ìṣẹ̀rùbàlú àti Ìdìtẹ̀gbàjọba ti wọ́n sì sọ ẹgbẹ́ tó ń darí, ìyẹn IPOB ní súúná oníjàádì.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×