
Lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ tí ó ga jù lọ ní ilẹ wa ti dá ẹjọ́ pé àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Rivers tí wọ́n fara mọ́ Mínísítà fún olú ìlú ilésà wa,Nyensom Wike lẹ́tọ̀ọ́ lábẹ́ òfin láti ta kọ́sọ́ sínú ẹgbẹ́ òṣèlú tó bá wù wọ́n láìpàdánú ìjókòó wọn; Gómìnà Siminalaye Fubara ti kọ̀wé sí wọn láti dìjọ ṣe ìpàdé àṣọyépọ̀ lójúnà bí ìjọba yóò ṣe ṣe èyí tó ti nípa bí yóò ṣe tẹ́ pẹpẹ àbá ètò ìṣúná ọdún 2025 fún àgbéyẹ̀wò.
Bí a kò bá ní gbàgbé, ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin elérò méjì tó fara mọ́ ọn ló tẹ́ pẹpẹ àbá ètò ìṣúná ọdún 2025 fún, tí wọ́n sì ti buwọ́ lù ú láìsọsẹ̀.Ṣé bí irọ́ bá ń lọ ní ogún ọdún, ọjọ́ kan ṣoṣo ni ododo yóò ba.Ní báyìí, iyán ti di àtúngún,ọbẹ̀ ti di àtúnṣe.
Lára àwọn ohun tó tún wà nínú lẹ́tà náà ni bí wọn ó ti ṣe rí ibì tó tẹ́jú dárdára máa ṣe ìpàdé ilé.Ti ẹ kò bá gbàgbé, ìjọba Fubara yìí ló wó ìlè ìgbìmọ̀ aṣòfin lulè ni kété ti èdè àìyedè láàrin àwọn ọmọ ilé àti Gómìnà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ète pé ìjọba fẹ́ tún ilé ìgbìmọ̀ aṣofin náà kọ́.Láti ìgbà náà ló sì ti ṣòro fún ilé láti rí ibi tó dára sí jókòó ṣe ìpàdé wọn.
Saájú ni ilé ti kọ lẹ́tà sí Fubara pé àwọn fún un ní wákàtí mejilélógójì láti dá àbá ètò ìṣúná ọdún 2025 tí wọ́n fọwọ́ sí ní ọ̀nà ẹ̀bùrú padà sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin.Èsì lẹ́tà náà ni Gómìnà dá padà tó bí ìpàdé yìí.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
