Ó ti dájú gbangba pé àwọn ọmọlẹ́yìn Èṣù káàkiri àgbáyé ti kó ara wọn jọ láti ṣe ọdún Èṣù lápapọ̀ nínú osù kìíní ọdún 2025.
Eredii ìpàdé yìí ni láti fi òye ohun tí wọ́n kà kún ẹ̀kọ́ òdì nípa ìgbàgbọ àwọn ènìyàn nipa Èṣu yé wọn.Wọ́n tẹ̀ síwájú pé Èṣù kìí ṣe oníbàjẹ́,ìkà àti ẹni burúkú gégé bí àwọn ẹ̀ṣìn àjèjì ti kọ́ wọn.
Ìgbàgbọ́ àwọn Eléṣù parapọ̀ ni pé àpéjọ náà yóò jẹ́ orisun ìmọ̀ fún gbogbo ènìyàn láti mọ ìyàtọ̀ láàrin Èṣù àwọn bàbá ńlá wa àti Sàtánì.
Bí ilaniloye yìí bá ń tẹ̀ síwájú tó sì ń wáyé lóòrèkóòrè, kò ní pẹ́ kò ní jìnnà tí àwọn ọmọ Naijiria lápapọ̀ yóò fi mọ ẹrú yàtọ̀ sí ọmọ láàrin Èṣù àti Sètáánì.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
