
Bí ọ̀rọ̀ tó ti ẹnu alága APC ní ilẹ̀ Nàìjíríà tíí tún ṣe gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Kano, Dókítà Abdullahi Ganduje jáde ní àná ní Sẹkitéríàtì ẹgbẹ́ náà tó wà ní ìlú Abuja bá jẹ́ òdodo,ó dà bí ẹni pé òpin kò ní pẹ́ dé bá ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP ní ìpínlẹ̀ Kano ní pàtó àti ilẹ̀ Nàìjíríà lápapọ̀.
Ọ̀rọ̀ yìí jáde lénu Ganduje nígbà tí àwọn ìgbìmọ̀ ẹgbẹ́ tó ń ṣe àtìlẹ́yìn fún Tinúbú ṣe àbẹwò sí i ní ọọ́fíìsì rẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí Ganduje ṣe wí,ọ ní tikéré-tikèrè ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP ni wọ́n ti fi ìfẹ́ hàn láti tọ kọ́sọ́ bá sìnú ẹgbẹ́ APC nítorí ilé ló jẹ́ fún gbogbo wọn.
Níwọ̀n-ìgbà-tí Rabiu Musa Kwakwaso tíí ṣe Olùdarí ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP ti ìfẹ́ hàn láti padà sí ilé, kò si ẹni náà ti yóò ṣe ohun tó yàtọ̀ sí èrò ọ̀gá wọn.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
