Ẹgbẹ́ ANBROAD sí Ọọ́fíìsì tuntun ní ìpínlẹ̀ Oǹdó.

Ẹgbẹ́ Akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ ní Nàìjíríà tí a mọ̀ sí ANBROAD, ẹ̀ka ti ìpínlẹ̀ Oǹdó ti ṣí ọọ́fíìsì titun.Ojúlé Kẹrìnléláàádọ́ta, agbègbè Àdìnlẹwà,ìdojúkojú Lékè Arts ni ọọ́fíìsì náà wà ni ìlú Àkúrẹ́.

Nígbà tó  ń sí ọọ́fíìsì náà, bàbá ẹgbẹ́ ANBROAD ní ìpínlẹ̀ Oǹdó, Àgbà oyè Ọláyàtọ̀ Aríbò kókè ìgbìmọ̀ aṣàkóso ẹgbẹ́ náà fún ẹ̀mí ìsiṣẹ́ṣìnlú tí wọ́n ní.Ó wá rọ̀ wọ́n láti  máa tẹ̀ síwájú kí wọ́n sì wà ní ìṣọ̀kan nítori bí ògiri kò bá lanu, Aláǹgbá kò lè wọ ibẹ̀.Kọmísánnà fún ètò ọ̀gbìn tẹ̀lẹ̀ náà wá jẹ́jẹ̀ẹ́ àtìlẹ́yìn rẹ̀ fún ẹgbẹ́ ANBROAD lóòrèkóòrè.

Àgbà Olóyè  Ọláyàtọ̀ Aríbò

Nígbà tí òun náà ń sọ̀rọ̀, Gómìnà ẹgbẹ́ ANBROAD ní ìpínlẹ̀ Oǹdó, Oyè Oyèdọ̀tun dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ànfàní tí Ó fún ẹgbẹ́ náà láti ní olú ilé iṣẹ rẹ ní ìpínlẹ̀ Oǹdó.Ó ní ohun tó ń gbé ẹgbẹ́ náà ró ni àtìlẹ́yìn ti kò lẹ́gbẹ́ tí àwọn atukọ̀ ẹgbẹ́ náà ń rí gbà láti ọ̀dọ̀ awọn ọmọ ẹgbẹ́.Ó wá fi àmì ìdánilójú hàn gbangba pé iṣẹ́ àtitukọ̀ ẹgbẹ́ yóò túbọ̀ rọrùn si pẹ̀lú ọọ́fíìsì tuntun náà.Ikán para pọ̀,ikán mọlé,èèrún para pọ̀,wọ́n mọ àgìyàn àti pé àìrìnpọ̀ ló ń jẹ ọmọ ejò níyà.  Oyèdọ̀tun wá pè fún ìtẹ̀síwájú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ láàrin àwọn ọmọ ẹgbẹ́ kí ẹgbẹ́ náà lè gbé ẹrù dé Àkẹ̀sán tíì ṣe baálẹ̀ ọjà.

Oyè Oyèdọ̀tun

Àgbà nínú àwọn Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ nnì, Olóyè Ìgè Jọ̀m̀gbọ kò sàìtẹ́ pẹpẹ ìrírí rẹ̀ fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ láti kọ́ wọn lọ́gbọ́n.Jọ̀m̀gbọ gbe ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́sẹ̀ pẹ̀lú bí ó ti sun àtìmọ́lé fún ọjọ́ méje gbáko nitori pé òun sọ ọ̀rọ̀ ọkùnrin kan tó hu ìwà ìbàjẹ́ lórí ètò gbajúgbajà tí a mọ̀ sí Ó gbèrò nígbà náà.Ó wá rọ̀ wọ́n láti jẹ́ àwòkọ́ṣe rere lẹ́nu iṣẹ̀ kóówa won nítorí àwọn ni dígí ti awọn ará ìlú ń wò.

Alàgbà Ìgè Jọ̀m̀gbọ́

Àwọn ènìyàn lọ́kan-ò-jọ̀kan ní wọ́n sọ̀rọ̀ ìyànjú nibi ayẹyẹ náà.Saájú ni gbajúgbajà ààfáà kan àti wòlíì kan ti fi àdúrà ya ọọ́fíìsì náà sí mímọ́

Lára àwọn  lóókọlóókọ láwùjọ tó péjú-pésẹ̀ síbi ayẹyẹ náà ni Aṣojú Gííwá ilé-iṣẹ́ Rédíó Nàìjíríà, Àkúrẹ́ ,Dúpẹ́ Isename, Gííwá Glow fm, Akure, Aládésanmí Oyèkànmi, Aṣojú Gííwá ilé-iṣẹ́ Fresh fm, Àkúrẹ́,Promise Inúmisàn , Alága àná fún àjọ Òsìṣẹ́ Rédíó, tíátà àtí Tẹlifísàn tí a mọ̀ sí RATTAWU ní ìpínlẹ̀ Oǹdó, Laurel Múbọ̀ Òjó,Àgbà ẹgbẹ́ Bísí Ajíbóyè Ṣọ́gigùn,Bàbá Àgbà àti àwọn léèkànléèkàn mìíràn láwùjọ .

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×