
Ẹgbẹ́ Akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí a mọ̀ sí ANBROAD ẹ̀ka ti ìpínlẹ̀ Oǹdó yóò ṣe ìpàdé wọn olóṣooṣù loni-in ní olú ilé iṣẹ ẹgbẹ́ wọn tó wà ní ìdojúkojú Lékè Arts ni agbègbè Àdìnlẹwà ní ìlú Àkúrẹ́.
Àtẹ̀jáde tí Alukoro ẹgbẹ́ náà,Adékúnlé Adéwùmí ti a mọ̀ sí Kẹ̀kẹ́ Àwàdà fọwọ́ sí sàlàyé pé agogo méta ọ̀sán ni ìpàdé náà yóò gbéra sọ.
Ò wá rọ gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ kí wọ́n péjú-pésẹ̀, kí wọ́n sì tètè dé sí ibi ìpàdé náà.Gbogbo ọjọ́ Ọjọ́bọ àkọ́kọ́ nínú osù ni ìpàdé ẹgbẹ́ máa ń wáyé.
Àrà ọ̀tọ̀ ni ti oṣù yìí nitori àwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìdàgbàsókè ẹgbẹ́ pàápàá jùlọ ọ̀rọ̀ nipa káàdì ìdánimọ̀ àti àbẹ̀wò ẹgbẹ́ sí àwọn ilé ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ bíi mélòó kan wà lára ohun tí wọn yóò pẹ̀ẹ̀kẹ́ lù nínú ìpàdé náà.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
