
Bíi fíìmù orí ìtàgé ló jọ nígbà tí àwọn Ajínigbé fi ọwọ́ taari ìpàkọ́ lèmọ́mù àti àwọn mẹ́sàn-án mìíràn sí inú ọkọ̀ ti won kó wọn ní papámọ́ra wà wọ́n lọ sínú igbó lẹ́hìn tí wọ́n ti já wọn ní ìrun Súbúì ti won ń kí lọ́wọ́ tán lọ́jọ́ ọjọ́bọ̀ ọ̀sẹ̀ yìí ni Sabo Birni ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Buchi ni ipinle Sokoto.
Àwọn tí wọ́n fura sí pé ó ṣe isẹ́ láabi náà ni àwọn oníjàádì Báńdíìtì.Alukoro àjọ Ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Sokoto,Ahmed Rufai tó fìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ ní ọ̀gá ọlọ́pàá Sabon Birni ló ta àwọn lólobó ọ̀rọ̀ náà.
Rufai ní àjọ Ọlọ́pàá ipinlẹ Sokoto sì ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wón sì ti da ogunlọ́gọ̀ àwọn ọlọ́pàá síta láti dóòlà àwọn olùjọ́sìn náà

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
