Èèmọ̀ Rèé o!Àkẹ̀kọ̀ọ́ Gún Akẹ́kọ̀ọ́ Ẹgbẹ́ rẹ̀ pa ní Àkókò.

Inú ìbànújẹ ni àwọn ènìyàn ipinlẹ̀ Oǹdó pàápàá jùlọ àwọn ará Anglican Grammar School,Ìkàrẹ́-Àkókó wà látàrí bíi ọmọbinrin kan tó ń jẹ́ Sandra ṣe gún akẹ́kọ̀ọ́ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Habib Salami pa nitori èdè àìyedè kékeré kan.

Ọ̀rọ̀ kékeré kan ló fa èdè àìyedè láàrin àwọn méjèèjì eléyìí tó bí Sandra nínú tó bẹ́ẹ̀ tó fi yá ọ̀bẹ lọ́wọ́ ọmọ ilé ìwé ìkọ́ṣẹ́ ọwọ́ tí a mọ̀ sí Technical College tó sì gún Habib titi tó fi gba ẹ̀mí lẹ́nu rẹ̀.

Wón ti gbé òkú rẹ lọ sí ilé ìgbókùúsí yi ilé-Ìwòsan ti Specialist Hospital.Nígbà tí wọ́n ti fi páńpẹ́ ọba gbé ọmọbìnrin ọ̀daràn náà lọ sí àgọ́ wọn.

Gbogbo akitiyan wa láti bá alukoro àjọ Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oǹdó, Funmilayo Ọdúnlámi sọ̀rọ̀ ló já sí pàbó

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×