
Àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Edo ti dìbò yan Gómìnà tuntun ti yóò máa ṣe àkóṣo ipinle náà fún ọdún mẹ́rin miiran.Onítọ̀hún ni Monday Peter Okpebolo.Ẹni ọdún mẹ́rìnléláàádọ́ta ni í ṣe.Óun sì ni olùdíje lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Faruk Kuta tíí ṣe Gííwá ilé-ẹ̀kọ́ gíga jùlọ Yunifásítì ìmọ̀ ẹ̀rọ tó wà ní Minna ní ìpínlẹ̀ Niger tíí tún ṣe ọ̀gá àgbà tó wà ní ìgbánnu ìkéde ìbò náà ló kéde rẹ̀ lẹ́yìn tó ti ní ìbò tó tó Ẹgbẹ̀rún lọnà ọ̀ọ́dúnrún ó dín mẹ́sàn-án àti ọ̀tàlélẹ́gbèta ó lé méje (291,667 votes)
Ẹni tí ó sún mọ ọn pẹkipẹki nínú ìdíje náà ni Asue Ighodalo ti ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tó ní ìbò Ẹgbẹ̀rún lọ́ná òjìléerúgba ó lé méje àti ọ̀rìnléerúgba ó dín mẹ́fà(247,274 votes). Nígbà tí Olúmìídé Akpata ń wọ́ ruru bọ̀ lẹ́yìn wọn pẹ̀lú Ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ìbò ó lé Ọ̀tàlélẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin àti meta(22,763 votes)
Èsì ìbò yìí ló fòpin sí gbogbo hílàhílo òsèlú tó gbòde kan ní ìpínlẹ̀ Edo eleyii tó gbẹ̀mí lénu àwọn ènìyàn bíi mélòó kan.
Láti ìgbà tí ilé ẹjọ ti dá Adams Oshiomole àti Olusegun Mimiko láre lọ́dún 2008 latari ẹjọ́ tí wọ́n pè tako ìjáwé Olúborí Osunboh àti Agàgú ti ẹgbẹ́ òṣèlú PDP nígbà náà ní ìbò Gómìnà àwọn ìpínlẹ̀ méjèèjì àti àwọn ìpínlẹ̀ mìíràn kò ti bá ẹgbẹ́ mu.
Nínú osù kọkànlá ọdún yìí ni ìdìbò sí ipò Gómìnà ìpínlẹ̀ Oǹdó náà yóò wáyé.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
