Èdè Òyìnbó ló kó mi ní papá mọ́ra;Àwọn Ònífíìmù èdè Gẹ̀ẹ́sì Máa Ń Pè mí sí iṣẹ́ …….Madam Ṣajẹ

Bí kò bá si ti pé àìgbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì mi, gbogbo ìgbà ni n kò bá máa kópa nínú àwọn fíìmù èdè Gẹ̀ẹ́sì ní ilẹ̀ yìí àti ní ilẹ̀ òkèèrè.

Ògbóhùntarìgì Afèdèsẹṣọ́ eléré tíátà ti gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Madam Ṣajẹ ló fí ọ̀rọ̀ òkè yìí léde nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí àkọlé ọ̀rọ̀ kan tó pè ní ‘Àwọn ohun tí ẹ kò mọ̀ nípa mi ‘ èyí tó fi léde lórí ẹ̀rọ ayélujára ayárabíàṣá rẹ̀ tí a mọ̀ sí X.

Madam Ṣajẹ sọ pé ìwé mẹ́fà péré ní òun kà kí òun tó bẹ̀rẹ̀ eré ìtàgé ní odún 1975.Ó ní tó bá jẹ́ pé òun ka ìwé jù bẹ́ẹ̀ lọ ni, òun kò bá ní anfààní láti sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì eléyìí tó jẹ́ ọ̀pákùtẹ̀lẹ̀ láti kópa nínú eré ìtàgé lédè Gẹ̀ẹ́sì.

Ó wá dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ibi tó ràn án lọ́wọ́ dé nínú eré ìtàgé tó jẹ́ iṣẹ́ tó yàn láàyò

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×