Ẹ Má ṣe Dágunlá;Ẹ̀tọ́ Yín ní láti Dìbò….Adélàmí

Igbákejì Gómìnà ìpínlẹ̀ Oǹdó,Ọláyídé Adélàmí ti pàrọwà fún àwọn ènìyàn ipinlẹ̀ Oǹdó lápapọ̀ pàápàá jùlọ àwọn ènìyàn Ọ̀wọ̀ ati agbègbè rẹ̀ láti jáde kẹ̀tíkẹ̀tí láti dìbò nínú ètò ìdìbò sí ipò Gomina tó ń lọ lọ́wọ́ ni ìpínlè Ondó.

Adélàmí fojú ọ̀rọ̀ yìí léde ní kété tó dìbò tán ni agbègbè ìdìbò Ìgboròkù 2 ,wọ́ọ̀dù kẹta Uníìtì Kerindinlogun ní ìlú Ọ̀wọ̀. Ní déédé agogo mẹ́wàá ku ìṣẹ́jú mẹ́ēẹ́dógún òwúrọ̀ ni igbákejì Gómìnà dé ibùdó ìdìbò tí o sì tó sori ìlà titi ti ó fí tó àkókò fûn láti dìbò.

Ní kété to sì dìbò tán ló bá àwọn oníròyìn sọrọ tó sì fí ìgbàgbọ rẹ nínú àjọ INEC láti ṣètò ìdìbò tó mọ́yánlórí hàn.Ó wá rọ tikérétikèrè láti jáde dìbò nítorí ojúṣe wọn ni gégé bíi ojúlówó ará ipinlẹ̀ Oǹdó

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×