Ẹ gbà mí oo!Bí ẹní lu aṣọ Òfí Ni Ìyàwó mi máa Ń Nà Mí oo

Ilé ẹjọ́ kọkọkọkọ kan ní ìlú Ìbàdàn ti sún igbẹ́jọ́ siwaju lórí ẹjọ́ tí Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ṣàká pé lórí bí ìyàwó rẹ ṣe máa ń nà án bí ẹni lu bàrà tó bá ti mú ọtí yó tán.

Ṣàká rọ ile ẹjọ́ kó tú ìgbéyàwó ọlọ́dún márùn-ún ti ó wà láàárín òun àti Sàdia ká nitori kó má baà gba ẹ̀mí òun. Ó ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọta lòún fi dá Sàdia lóko òwò sugbọ́n ọtí ló fí gbogbo rẹ mu tán.

Ṣàká tẹ̀ síwájú pé bí ìyàwó òun bá ti mu ọti yó tán ni yóò máa tọ̀ kiri bíi Àkèré.Lẹ́hin èyí, ní yóò dá òun dọ̀bálẹ̀ tí yóò sì máa to égba sí òun nídìí. Ó wá rọ ilé-ẹjọ́ kí ó tú ìgbéyàwó àwọn ká.

Nígbà tí òun náà ń rojọ́, Sàdia ní Ahun,Ọ̀lẹ àti Aláìmètò ni Ṣàká.Ó ní irọ́ ńlá ni ó ń pa,kò dá òun ní oko-òwò kánkan. Igba náírà péré ló máa ń fún òun ní owó ọbẹ̀ ní bí nnkan tí le tó yìí.O ní Obìnrin kìí dúró nílé è nitori ìwà burúkú rẹ̀ àti pé òun ni obinrin keje ti yóò lé lọ.O wá rọ ilé-ẹjọ́ kó tú ìgbéyàwó àwọn ká.

Lẹ́hìn àwíjàre tọ̀tún-tòsì, ilé ẹjọ́ wá sún ìdájọ síwájú sí oṣù Kejìlá

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×