
Bámúbámú ni gbogbo ọ̀nà igboro ìlú Lokoja kún fún àwọn olùfẹ̀hónú hàn tí gbogbo wọn gbé pátákó Ajúwe tó ń kìlọ̀ fún àjọ EFCC kí ó fi Yahaya Bello lọ́rùn sílẹ̀ lọ́wọ́ kóówa wọn.
Wọ́n ní Ìgunnu ló ni Tápà,Tápà ló ní ìgunnu.Yahaya Bello ló ní àwọn, àwọn làwọn ni Yahaya Bello, owó àwọn ló ná,kín wá ni àjọ EFCC fẹ́ pa ara rẹ̀ lé lórí? Nígbà tí Alára ní ara kò ro òun, kín ló dé tí wọ́n fi ń kí í kú áìsùn kú àìwo?

Gbogbo àwọn ẹ̀yà tí ó jẹ́ ọmọ ìpínlè náà bíi Ebira,Igala àti Yorùbá ní wọ́n kópa nínú ìwọ́de àlálàáfíà náà.
Obìnrin kan tí ó ń jẹ́ Fatimah tó jẹ́ ẹ̀yà Ebira ní ọ̀rọ̀ náà ti ní ọwọ́ kan òsèlú nínú àtí pé gbọningbọin ni gbogbo ènìyàn ìpínlè Kogi wà leyin Gómìnà àná ọ̀hún.

Wọ́n wá rọ Ààrẹ Bọ́lá Tinubu kó dá sí ọ̀rọ̀ náà.Bákan náà ni Arábìnrin Deborah tó jẹ́ ẹ̀yà Igala ní kò sí Gómìnà tó ṣe iṣẹ dáradára to tẹ́ ará ìlú lọ́rùn tó Yahaya Bello nínú ìtàn ipinle Kogi.Fún ìdí èyí, kí ajọ EFCC forí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jìn in.
Ní kété tí Bello tí kúrò lórí àlééfà ló ti ń sá fún àjọ EFCC nitori ẹ̀sùn òbitibiti owó bílíọ̀nù náírà owó ìpínlẹ̀ náà tí wọ́n fi kàn án pé ó pa ní póńpó.Ẹẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni pàkúté àjọ náà ti mú un ní àmúbọ́ pẹ̀lú àtìlẹ́yìn àsìlò òfin aṣẹ̀málù Gómìnà Ododo tíì ṣe Gómìnà ìpínlẹ̀ náà báyìí.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
