Ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ nípa májẹ̀mú titun ní ilé ẹkọ gíga julọ Yunifásítì Adékúnlé Ajáṣin tó wà ní Àkùngbá-Àkókó, Olú Alànà ti sọ yanya nígbà tó ń dánilẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé àpilẹ̀kọ rẹ̀ tó fi sọrí ìfinimawo sí ipò ọ̀jọ̀gbọ́n,ẹlẹ́ẹ̀kẹrìndínlọ́gbọ̀n irú rẹ̀ eléyìí tó pe àkòrí rẹ̀ ní “Yíyọ okùn ẹrú lọ́rùn ilẹ̀ Adúláwọ̀ pẹ̀lú ìhà tí wọn mú kí Májẹ̀mú titun kọ sí wa” tó wáyé ní gbọ̀ngàn ńlá ti ilé ìwé náà.

Igi ìwé yìí ni kò sí ìbi kan pàtó tó dá ọkùnrin lọ́wọ́ ko láti má ṣe fi ju ìyàwó kan lọ nínú májẹ̀mú titun.Ó wá júwe àṣà náà bíi Àdábọwọ́ àwọn òyìnbó àmunisin láti ju ìran Adúláwọ̀ sí inú ìdè ayérayé.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìhùwàsí àti ìsesí Jésù kristi gẹ́gẹ́ bó ti fara hàn nínú májẹ̀mú titun, Ọ̀jọ̀gbọ́n Alànà ní Ajàfẹ́tọ̀ọmọnìyàn ni Jésù tó wà nínú bíbélì,kÒ gba ìgbàkugbà,kódà kìí dara pupo pẹ̀lú àwọn ìjọba tó ń ní ará ìlú lára.

Lórí ìdámẹ́wàá ,ọrẹ àti àwọn owó miiran ti ìjọ óde-òní dọ di bárakú láìnáání ipò tí àpò kóówá wà.Ó ní kí wọ́n yé máa lépa ayé àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀ ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ kí wọ́n máa wá ọ̀nà tí ìṣẹ́ òhun ìyà tó ń gun àwọn ènìyàn bíi ẹní gun ẹṣin yóò ṣe dìtàn láwùjọ Kristẹni ní pàtó àti Nàìjíríà lápapọ̀.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Olú Alànà wá ṣe àpèjúwe ibí tí Jésù ti fi àkàrà márùn-ún àti ẹja mẹ́fà bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn nínú bíbélì.Bákan náà ló sì tún júwe ibi tó ti ń se ìwòsàn láìgbẹ̀jẹ́.Ó ní àpẹrẹ rere yìí ló yẹ kí àwọn ìjọ máa mú lò dípò ki wọ́n máa fún àwọn ọmọ ìjọ wọn gbẹ nípasẹ̀ ìdámẹ́wàá,ọrẹ àti àwọn òkan-o-jòkan owó pẹ̀lú èròngbà láti kọ gbọ̀ngàn tó lè gba ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ ènìyàn

Ó tún pàrọwà síwájú síi pé kò yẹ kí ẹ̀sìn pa àṣà wa rẹ́ nítorí àsà àti ìse ló ń júwe bí ènìyàn ti ri.A kò gbọdọ takété sí ohun tó sọ wá ní orúkọ Yorùbá tí a ń jẹ́.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀,Gííwá ilé ẹ̀kọ́ gíga julọ Yunifásítì Adékúnlé Ajáṣin,Ọ́jọ̀gbọ́n Olúgbéńga Ìgé lu Ọ̀jọ̀gbọ́n Alànà lọ́gọ ẹnu fún akada takuntakun tí Ọ̀jọ̀gbọ́n náà ṣe.Ó ní Is ọpọlọ náà yóò ṣe iṣẹ́ olùdáǹdè fún ogunlọ́gọ̀ ènìyàn tí wọ́n ti wà ní ìkòríta kòyémimọ́ nínú ẹ̀sìn ìgbàgbọ́.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
