
Kannakánná tó ń na ọmọ ẹ̀gà láàrin ìyàwó gómìnà ànà ní ìpínlẹ̀ Oǹdó,Betty Akérédolú àti Kọmísánnà fún ètò ìsúná Abilékọ Ọmọ́wùmí Isaac ti kúrò ní dúkùú, ó ti wá di ìjà gidi báyìí ní bí àwọn méjèèjì ti ń sọ àkàṣù ọ̀rọ̀ tòhun tèébú tí a dé ní adé èpè ránsẹ́ sí ara wọn.
Gbáàs-Gbòós náà pọ débi pé níṣe ni àwọn méjèèjì ń ta oùn sí ara wọn gẹ́gẹ́ bí orogún méjì ṣe máa ń ṣe bí ìjà bá pa wọ́n pọ̀ ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ ọkọ wọn. Bí aya Àkétì ti ń pe aya Isaac ní àwọn orúkọ tí kò ṣe é gbọ́ létí bíi:Dágundágun,Gbọkọgbökọ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orúkọ Àgbọ́-ṣe-hàà! mìíràn ni aya Isaac náà ń jù ú padà sí nígbà tí kìí ṣe pé òun náà gbé ẹnu rẹ̀ fún alágbàfọ̀, ó ní Betty Akérédolú jẹ́ aláìlójútì ẹ̀dá tó yẹ kó máa lo sáà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n lọ́wọ́lọ́wọ́ lórí ẹ̀ṣùn apànìyàn nítorí ẹ̀rí àrígbámú wà pé Òun ló pa ọkọ rẹ̀.
Ó tẹ̀ síwájú pé kò sí ààyè ilẹ̀kẹ̀ ní ìdí adìrẹ ní ìpínlẹ̀ Òǹdó, ìyàwó Gómìnà kankan kò lè jẹ irúfẹ́ ayé alâbátá ti Betty Akérédolú jẹ ní ọ́fíìsì mọ́ ní ìpínlẹ̀ náà. Ó ní bí aya Akérédolú kò bá sọ́ra, òun yóò gbe lọ sí kóòtù adájọ láti wá wi tẹnu rẹ̀ lórí ẹ̀ṣùn ọlọ́kan-ò-jọ̀kan ti ó fi kan òun; nítorí wọn kò bí Ṣórin mọ́ ẹja.
Kọmísánnà náà wá rọ àwọn ènìyàn kí wọ́n má ṣe tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ Betty nitori ọ̀rọ̀ tí kò ní ẹsẹ̀ nílẹ̀ ni.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
