Babańgbẹ̀jọ́ọ mi ló fún mí ní Mílíọ̀nù Marun-un Náírà (₦5m) Kí n fún Agbẹjọ́ròàgbà láti bá mi ra Àforíjìn…Bobrisky

Bobrisky

Idris Olarewaju Okuneye tí a mọ̀ sí Bobrisky ti sàlàyé pé Babańgbẹ̀jọ́ọ òun ló bá òun san owó tó tó Mílíọ̀nù Marun-un Náírà nínú Mẹ́wàá tí Agbẹjọ́rò àgbà ní òun gbọ́dọ̀ san láti rí ìyọ̀nú ìjọba láti forí ẹ̀ṣẹ̀ òun jìn.

Martins Otse tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Very Dark Man ló fojú fán-án-rán ti àkáálẹ̀ ọ̀rọ̀ yìí wà léde lọ́jọ́ ajé ọjọ́ keje oṣù yìí.

Ó ní ó dá òun lójú pé Bobrisky kò sun oorun ọjọ́ kan ló kéré jù nínú ẹ̀wọ̀n.Inú ilé kan lẹ́gbẹ̀ẹ ọgbà ẹwọn náà ló ti ń mìlíkì.

Bobrisky sọ bayii pé “Ọ̀rẹ́,má jẹ́ kí n tàn ọ́,igbádùn ló bá dé fún mi níbi tí mo wà nítorí ilé kan ti a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọgbà ẹwọn ni mo ń gbé.Wọn kò kó mi pọ̀ mọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n kankan.Owó ló n ṣe iṣẹ́ yen, Babańgbẹ̀jọ́ọ mi ti settle àwọn lọ́gàálọ́gàá,kan-in-kan-in ò gbọdọ̀ ta mín,èèrà kò gbọdọ̀ rìn mín pẹ̀lú.” Ọ̀rọ̀ inú fọ́nrọ́n tí Very Dark Man fi léde nìyẹn.

Gégé bí Very Dark Man ṣe sọ,èrèdíi èri-maa-jé-mi-niso tí òun fi nfìdíi rẹ̀ múlẹ̀ pé Bobrisky kò sùn ní ẹ̀wọ̀n ni láti pinnu ìwà àjẹbánu tó ti jàrábà àwọn lọ́gàálọ́gàá ibùdó atóríṣe nílẹ̀ Nàìjíríà.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×