
Bí a kìí bá wí kí ẹnu ó wú,oko tó ń jágún kò jágún mọ́;Kọ́léoṣó ti di Kọ́léẹyẹ,Sàlàkọ́ sì ti di Sàlákọ̀ ní Ìlú Arárọ̀mí .Ní kúkúrú èdè,ara kò rọ ará Arárọ̀mí mọ́ ooo!
Ó ti tó bíi ọdún mélòó kan ṣẹ́yìn ti Òkun ti ń gbé ìlú Arárọ̀mí mì dírẹ̀dírẹ̀.Bí ènìyàn bá wá dé ìlú yìí ni àsìkò tí a wà yìí, bí onitọ̀hún bá jẹ orí ahun,dandan ni kí orí rẹ wú ní bí omi ti gbalé-gboko lówó ìlú náà.
Agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Ẹsẹ̀-Odò ní ìpínlẹ̀ Oǹdó ni Arárọ̀mí wà.Ilú náà wà lára àwọn ìlú tó ń pèsè èpo rọ̀bì ní Nàìjíríà.Ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn oníròyìn tí fẹnu kan òrò Araromi yìí sùgbón tí kò sí ohun tí ó yí padà.
A wá tún ń rọ awọn ijọba láti ìpínlè dé Àpapọ̀ láti tètè wa nǹkan ṣe sí ọrọ náà.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
