
Àwọn Ìgbìmọ̀ Aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun tó wà ní ìlú Ìré ti ti ilé ìwé gíga náà pa.Ohun tó fa ìdí abájọ tí wọ́n fí ti ilé ìwé náà pa ni gbódónrósọ tó ṣúyọ láàrin àwọn igun ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn méjì tó wáyé ní ẹnu ìloro ilé ìwé náà ní àná òde yìí
Ìjà náà gbóná girigiri débi wí pé òkúdìrẹ kò mọ olùtu.Ńṣe ni àwọn méjèèjì ń dá iná ìbọn yá ara wọn sùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹni tí kò rà ló sán.
Ṣé olójú kò ní la ojú rẹ̀ sílẹ̀ kí Tàlùbọ̀ kó sí í lójú, ìdí rèé tí àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ aláṣẹ ilé ìwé gíga náà fi tí i pa kí oníkálukú kọjá lọ sí ilé rẹ̀.
Gẹgẹ bó ti wí, Ọ̀mọ̀wé Tọ́pẹ́ Abíọ́lá tíì ṣe ọgá àgbà kan ní ilé ẹ̀kọ́ gíga náà ní bí kò bá sí tí àwọn ẹ̀ka tó ń dá ṣẹ̀ríà fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn tó wà ní ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá tí wọ́n tètè dá sí ọ̀rọ̀ náà ni, nǹkan kì bá bàjẹ́ kọjá ààlà.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
