Àwọn Èrò Mẹ́kà ti ń múra ní ìpínlẹ̀ Oǹdó.Kódá,Wọ́n tí gbabẹ́rẹ́

Ní ìpínlẹ̀ Oǹdó

Àwọn èrò tó ń lọ sí Saudi Arabia láti ìpínlẹ̀ Oǹdó ti ṣetán báyìí nipasẹ ìgbáràdì ọlọ́kanòjọ̀kan.

Lára ìgbáradì náà ni kikọ nipa ẹ̀sìn, ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa èèwọ̀ àti ẹ̀tọ́ tí a lè ṣe ní ilẹ̀ Lárúbáwá.Pabambarì rẹ̀ wá ni gbígba abẹ́rẹ́ tó lè dènà àwọn àìsàn bíi ibà Jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀,abbl

Okòólélẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (720) ni àpapọ̀ àwọn tó fẹ́ lọ sí ilẹ̀ mímọ́ ní ìpínlẹ̀ Oǹdó nínú èyí tí okọ̀ólélọ́ọ̀ọ́dúnrún(320) ni àwọn Obìrin nígbà tí irínwó (400)jẹ́ ọkùnrin .

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, alága ìgbìmò tó ń ṣètò ìrìnàjò Mẹ́kà sọ pé igbimọ náà ti gbáradì láti mú kí ìrìnàjò tí ọ̀tẹ̀ yìí dùn kó sì ní arinrin.

Ọjọ́ márùndínlógójì ní wọ́n yóò lò ní Sáúdí Arábíà.Ọjọ́ kẹwàá oṣù karùn-ún ọdún yìí ni àwọn Alhaji ati Alhaja náà yóò tẹkọ̀ létí lọ sí ìlù Ìlọrin níbí tí wọn yóò ti fi bàálù gbé wọn lọ sí Saudi Arabia ní ọjọ́ kọkànlá, Kejìlá àti ìkẹtàlá oṣù karùn-ún ọdún yìí.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×