
Aláàfin ìlú ọ̀yọ́,Ọba Akeem Abímbólá Ọ̀wọ́adé ti rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà lápapọ̀ láti gba àlàáfíà láàyè ní ọ̀nà wọn gbogbo. Ó ní Àdáni wáyé tó dá wa sí orilẹ èdè yìí ní ìdí pàtàkì tó fi ṣe bẹ́ẹ̀.
Ọjọ́ Sátidé ìjẹta ló fojú ọ̀rọ̀ yìí léde lẹ́yìn tó parí ètùtù tii sọni dí ọba tó wáyé ni ìpẹ̀bí ní Kòso, ẹ̀yìn èyí ni wọ́n dé adé Sàngó lé e lórí fún ìgbà àkọ́kọ́.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀,ó kí àwọn mùsùlùmí kú ọdún ìtúnu;Ọ rọ̀ wọ́n láti mú gbogbo àkóónú ẹ̀kọ́ tí oṣù Ramadan kọ́ wọn lò.kí wọ́n tẹ̀ síwájú láti máa gbé ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn gbogbo.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
