Àjọ Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oǹdó ti Gbé DPO Ìgbàrà-Òkè tí wọ́n fẹ̀sùn Olè kan Kúrò

Wilfred Afọlábí
ọ̀gá ọlọ́pàá ìpínlè Oǹdó

Ọ̀gá Ọlọ́pàá ipinlẹ Oǹdó, Ọ̀gbẹ́ni Wilfred Afọlábí ti pàṣẹ kí wọ́n gbé DPO Ìgbàrà-Òkè, Ọ̀gbẹ́ni Gàníyù Dáwódù kúrò ní ìlú náà lẹ́yẹ-ò-sòkà.

Ìgbésẹ yìí ló tẹ̀lé ìfẹ̀hónúhàn kan tí àwọn ọ̀dọ́ ìlú náà ṣe nínú èyí tí wọ́n ti fẹ̀ṣùn kan DPO ọ̀hún pé olè,Ọ̀pọnmi-òkè-rú-todò àti Adárúgúdù sílẹ̀ ni.

Bi-o-tilẹ̀-jẹ́-pé alága ìjọba ìbílẹ̀ Ìfẹ́dọ̀rẹ́ ní Ìgbàrà-Òkè ti pe àwọn tí saájú pe àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn láti yanjú ọ̀rọ̀ náà ní ìtùbí-ìnùbí ṣùgbón ọ̀rọ̀ náà ti yíká orí ayélujára.

Ní kété tí Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Oǹdó ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà ló sì tí gbé ìgbìmọ̀ ti yóò olùwádìí dìde, ṣùgbọ́n láti má ṣègbè lẹ́yìn igun kankan nínú àwọn méjèèèjì, àjọ Ọlọ́pàá pàṣẹ kí Gàníyù Dáwódù lọ rọọ́kún nílé ná.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×