
Ìwọ lò ń ṣe mí,ìwọ lò ń gbà mí, báwo la ṣe ń dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹni tó ń ṣeni tó tún ń gbani?Ṣé ká má purọ́ tan ara wa jẹ,láìfàbòsí sọ igbá àlapà di igbá lúúrú; ọtá gedegbe ni awọn òyìnbó jẹ́ sí wa ní ilẹ̀ Adúláwọ̀.
Etí mélòó ló ń gbọ́ pé àwọn àjọ USAID ń ná owó tó lórúko láti ṣe onígbọ̀wọ́ fún awọn Al-qaeda,Boko haram àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àjọ Àṣẹ̀rùbàlú mìíràn?
Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin aṣòfin ilẹ Amẹ́ríkà, Scot Perry ló fojú òrò yìí léde pẹ̀lú ẹ̀ri tó dájú.Koda, ó fi ẹ̀ṣùn kan àwọn ìjọba tó ti kojá ní ilẹ Amẹ́ríkà

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
