Ah! Ó mà ṣe o!Olówó fowó ra ikú;Alágbàṣe ṣá Ọ̀gá rẹ̀ pa ní Oko Oǹdó.

Gógó ni abúlé Láòṣò nítòsí Lájé ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Ìwọ̀ òòrùn Oǹdó kan níbẹ̀rẹ̀ ọ̀ṣẹ̀ yìí.Ohun tó mú ìkorò bá ayé abúlé náà ni ikú obinrin kan ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Arabinrin Ládùgbà

Alágbàṣe obinrin yìí ló fi àdá sá a pa nígbà tó ń ti ọ̀nà oko bọ̀.Bí ó sì ti pa á tán ní ẹ̀rí ọkàn kò jẹ́ kó gbádùn títí tó fi lọ sàlàyé ní abúlé pé òun pa ọ̀gá òun sí ọ̀nà oko.

Àwọn ará abúlé tẹ̀le dé ibẹ̀, wọ́n ba òkú ìyà náà tí ó fi ewé bö ó lori sí.Mo kò ó a máa ní àpèjúwe, gẹ́gẹ́ bó ti wí, ìdí pàtàkì tó fi pa Abilékọ Ládùgbà ni pé ó ń tẹnu mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ olè jíjà tó ṣẹ̀ nígbà dírẹ̀ sẹ́yìn nígbà tó jí obì ìyá náà ká Ṣùgbọ́n tó ti bẹ̀bẹ̀ fún àforíjì.

Ní abúlé Láòṣò,lílé ni wọ́n máa ń lé ẹni yòówù tó bá ti jalè kúrò ní abúlé náà.Bóyá kò fé kí wọ́n lé òun kúrò ní abúlé ló se pa ẹni ẹlẹ́ni.

Àjọ Ọlọ́pàá ipinlẹ Oǹdó ti fìdí ọ̀rọ̀ naa múlẹ̀.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×