
Gómìnà àná ni ìpínlẹ̀ Edo, Adams Oshiomole ti sọ yanya pé Alájẹfáwo ẹ̀dá tó ń jiyán tán la odó dáná ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Edo, Godwin Obaseki.
Nínú ìfòròwánilénuwò kan tó ṣe lórí ẹ̀rọ Móhùnmáwòrán Arise TV ló ti fojú ọ̀rọ̀ yìí léde láìpẹ́ yìí.
Oshiomole tẹ̀ síwájú pé gẹ́gẹ́ bíi ajá elékùúkù ni Gómìnà náà ṣe ń kanra mọ́ gbogbo ènìyàn.Bó ti ń bá Ọba jà, ló ń kan ìjòyè lábùkù, Bó ṣe ń dá aṣọ ìyà ró Mẹ̀kúnnù, ló ń ju òkò ẹ̀tẹ́ sí Olówó . Tako-tabo ló ń gba ẹ̀bùn ìfìyàjẹni láti ọwọ́ Obaseki.
Ìwà Aláṣokan yìí ló gba aṣọ iyì òhun ẹ̀yẹ lọ́rùn rẹ̀ tó sì já a sí ìhòòhò gelete.Ṣé ẹ kò sì gbàgbé pé àgbájọ ọwọ́ la fi ń sọ̀yà àti pé àìjéjì ọwọ́ kò gbé igbá dórí.
Gbogbo àwa tí Ọlọ́run lò fún un láti wọlé sáà àkọ́kọ́ la di Aláìmọ̀íṣe mọ́ ní kété tí ó wọlé tán.Nígbà tó fẹ́ díje ṣáà ẹlẹ́ẹ̀kejì, Wike àti àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú ẹgbẹ́ Òṣèlú PDP ni wọ́n pọ̀n ọ́n,ti wọ́n gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ lé orí.Mo dákẹ́ nígbà náà nítorí mo mọ̀ pé pàsán tí a fi na ìyáálé ń bẹ lájà fún ìyàwó àti pé kò sí bí a ti lè ṣe ebòlò ti kò ní run àyán.Gbogbo wọn ló padà kàn lábùkù.
Mo gbọ́n tán,mo mọ̀ tán rẹ̀ pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tó fi ń wo gbogbo ènìyàn bíi òmùgọ̀.Ẹni tó gbọ́n, tó sì ní ará yòókù kò gbọ́n gan-an ni baba Wèrè nítorí pé ọgbọ́n tó bá fo àràbà tó bá fo òro,ẹ̀hìnkùlé agọ̀ ni yóò ti balẹ̀.
“Àwọn ènìyàn ipinlẹ̀ Edo ti fi ìbò wọn sọ̀rọ̀, ó sì dá mi lójú pé wọn kò ni kábàámọ̀” Oshiomole ló sọ bẹ́ẹ̀.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
