
Èèkàn Olórin fújì nnì tíì tún ṣe ọba orin fújì Bọ̀ǹsúè ló ti pé ọgọ́ta ọdún lókè erùpẹ̀.Ogunlọ́gọ̀ àwọn ènìyàn ńláńla ní àwùjọ ló ti ń rọ̀jò ìkíni kú oríire sí Jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́nìwà olórin náà .

Lára àwọn tí wọ́n ti kí Ọ̀gá fújì náà kú oríire ni Ààrẹ ilẹ̀ Nàìjíríà,Bọ́lá Tinúbú.Nínú iṣẹ́ ikinikuoriire rẹ̀ tó rán Bayọ̀ Ọnànúgà sí Adéwálé Àyúbà.Tinubu ṣe àpèjúwe rè bíi olórin ti orin rẹ̀ ń kọ́ni lọ́gbọ́n kọ́ni lóye.
Nínú ọ̀rọ̀ rè,ọ ní ‘Láti ìgbà tí ọmọ Alimọ́tù Sàdía ti bẹ̀rẹ̀ orin lẹ̀ni ọdún mẹ́tàdínlógún la ti mọ pé àṣeyè ti alákàn ń ṣepo ni yóò ṣe nítorí kò fi ìgbà kankan fi iṣẹ́ rẹ̀ ṣe àwàdà rí.’ Ààrẹ wá ṣe ádùrá pé pípẹ́ lowú ń ṣe ilé arọ́, kí ọba orin fújì Bọ̀ǹsúè ó ọ láyé.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
