Àṣejù Baba Àṣetẹ́;Ọba Olórílé ti Orílé-Ifọ̀ fi Ìwà Rádaràda Lé ara Rẹ̀ Lórí Ìtẹ

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ògùn,Dàpọ̀ Abíọ́dún ti pàṣẹ kí Olórílé ti Orílé-Ifọ̀ ní ìjọba ìbílẹ̀ Ifọ̀ ní ìpínlẹ̀ ògùn,Ọba Sẹ̀míù Ògúnjọbí pé kó lọ rọọ́kún nílé fún odidi oṣù mẹ́fà titi tí ìgbìmọ̀ tó ń ṣe ìwádìí lórí ìwà burúkú tí Ọba náà hù sí Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ààrinola Abraham Love yóò fi jábọ̀ ìwádìí wọn fún ìjọba

Olùrànlọ́wọ́ sí Gómìnà ìpínlẹ̀ Ògùn, Dàpọ̀ Abíọ́dún lórí Ìbánisọ̀rọ̀, Káyọ̀dé Akínmádé ló fi ojú ọ̀rọ̀ yìí léde ní ìlú Abéòkúta.

Gẹ́gẹ́ bí ó ti wí, Kọmísánnà fún ọ̀rọ̀ oyè àti ìjọba ìbílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ògùn, Ganiyu Hamzat ló ránṣẹ́ pé àwọn méjèèjì tó sì gbé ìgbìmọ̀ kalè lórúko Gómìnà lẹ́yin tó gbọ́ ẹjọ́ lẹ́nu tọ̀tún-tòsì wọn.Ki ìwádìí náà lè lọ gééré, wón ni kí Kábíyèsí yẹra lórí àpèrè fún osù mẹ́fà tí ìgbìmò náà yóò fi fi àbọ̀ ìwádìí wọn léde.

Àṣẹ ìjìyà tí wọ́n fún ọba yìí wà ní ìbámu pẹ̀lú òfin Lọ́balọ́ba àti ọ̀rọ̀ oyè jíjẹ ti ìpínlẹ̀ Ògùn.

Ẹ̀wẹ̀, àwọn Ajàfẹ́tọ̀ọmọnìyàn tí a mọ̀ sí CDHR ,ti sáájú fi ìwé ẹ̀ṣùn ránṣẹ́ sí ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá nílẹ̀ wa ,Káyọ̀dé Ẹgbẹ́tókun pé kí àwọn ọlọ́pàá gbé Ọba Sẹ̀míù Ògúnjọbí lori ẹ̀ṣùn pé ó tẹ ẹ̀tọ́ ìjọ́mọnìyàn Ààrinọlá Abraham mọ́lẹ̀ nípa sísọ ọ̀rọ̀ Kòbákùngbé sí i àti nínà-án bí ẹni na bàrà láàfin rẹ̀.

Nìgbà tó ń sọ̀rọ̀, Ọ̀gbẹ́ni Abrahamu ní jẹjẹ ni òun ń kọjá lọ ní ọjọ́ náà ti Kábíyèsí pe oun, Òun sì da lóhún, ṣùgbọ́n sí ìyàlẹ́nu òun, àwọn ọ̀rọ̀ tí òun kò mọ owó mọ ẹsẹ̀ ni wọn wé mọ́ òun lọ́rùn tí wọn kò sì jẹ́ kí òun wí tẹnu òun ti wón fi ń na òun bíi ejò àìjẹ.

Ó wá rọ ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn kí wọ́n má ṣe jẹ kí ìyà náà jẹ òun gbé nitori Òun kò mọ ẹnikan sugbon kabiyesi mọ eniyan nitori ọ̀gá Ọlọ́pàá tẹ́lẹ̀ ni í ṣe

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×