Irọ́ Gedegbe ni oo! Ìjọba Kò yọ alága INEC nípò…..Ọọ̀fíìsì Ààrẹ

Bí ọba kan kò bá kú,ọba kan kò jẹ.Ìjí kò sí ní jà titi kó da omí inú àgbọn nù.Gbogbo àwọn àsamọ̀ yìí ń tọ́ka sí pé  mìmì kan kò ní Mamud Yakubu tíì ṣe alága àjọ INEC ní Nàìjíríà titi ti yóò fí ló sáà rẹ̀ tán.

Àwọn olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún Ààrẹ Tinúbú lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn ìgbàlódé, Ọ̀gbẹ́ni Otega Ogra àti olùrànlọ́wọ́ Ààrẹ mìíràn, Ọ̀gbẹ́ni Daniel Bwala ní wọ́n ti ṣẹ̀ ìròyìn tó hùyẹ́ tó ń fò káàkiri pé Ààrẹ Tinúbú ti yọ Yakubu nípò láti yan  elomiran ní igbaradi fún ètò ìdìbò gbogbogbo ọdún 2027

Nínú ìpàdé oniroyin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ti àwọn méjèèjì ṣe ni ilu Abuja ni wọ́n ti fí ojú ọ̀rọ̀ yìí léde.Wọ́n ni àwọn oníbàjẹ́ ènìyàn kan tí wọ́n kò fẹ́ nǹkan  rere ni wọ́n ń pin ọ̀rọ̀ náà ká.

Wón wá rọ àwọn ọmọ Naijiria láti má ṣe gba sùnmọ̀mí náà gbọ́.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×