Àwọn ènìyàn wọ́de tako ìjọba Trump;Wọ́n ní ìjọba Aninilára ni

Ní báyìí,ó dà bí ẹni pé bàtà ìjọba Donald Trump tíí ṣe Ààrẹ ilẹ̀ Amẹrika ti ń ró kanlákanlá jù báyìí nitori òkan-ò-jọ̀kan ètò aninilára tó ń gbé bọ́ síta ní kété tó ti gun orí àléfà ìjọba láti inú oṣù kínní ọdún yìí.

Bí a kò bá ní gbàgbé, ní gbàrà tí ó ti gorí àlèéfà ló ti yọ ọwọ́ Kílàńkó ilẹ̀ Amẹrika kúrò nínú oríṣiríṣi ètò ìrànwọ́ onírúurú tí a mọ ilẹ̀ náà mọ̀ láti ìgbà ìwáṣẹ̀.Àwọn ìrànwọ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè Adúláwọ̀ àti àwọn mìíràn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dìdelè nipasẹ àwọn àjọ bíi USAID, UNESCO, WHO àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.

Yàtò sí èyí, ó tún gbógun ti àwọn àjèjì.Ó ní kí kóówá kọrí sí ilú rẹ̀, àjò kò sáà ní dùndùndùn kí onílè má relé pàápàá jùlọ àwọn tí ìwé ìgbélù wọn kù dírẹ̀ káà tó.Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Yunifasiti ni wọ́n ti dì ní Àpáǹyáká lọ sí ilú wọn láìrò tẹ́lẹ̀.

Èyí tó wá bí àwọn ènìyàn nínú jù lọ ni ọgbọ́n tó ń ta láti mú kí ilè Ukraine jawà sílẹ̀ fún ilẹ̀ Russia.Bákan náà ni Trump ń làkàkà láti taari ìjọba ilẹ̀ Canada tó ti wà lábé UK tipẹ́tipẹ́ sí abẹ Amerika.

Ìdí sì rèé ti àwọn ènìyàn fí ń fi ẹ̀hónú hàn yíká Amerika àti àwọn orílẹ̀-èdè bíi UK,CANADA àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.

Wọ́n fi ẹ̀ṣùn kàn pé ìjọba kàn-ànńpá àti bámúbámú ni mo yó ló ń ṣe . Àwọn ọlọ́rọ̀ olówó ló tún ń lówó síi nígbà tí ó wọ bùbá àti agbádá ìyà fún àwọn ènìyàn,

Bí ọ̀rọ̀ bá dé ojú rẹ̀ tán,,ìgbín fúnra rẹ̀ a máa pòṣé, ìdí rèé ti àwọn ènìyàn fi fọ́n pẹ̀ẹ̀rẹ̀pẹ̀ síta láti jáwé akìwọwọ fún ìjọba Aninilára.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×