Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tẹ́lẹ̀, ọ̀mọ̀wé Victor Ọmọlolú Olúnlọ́yọ̀ ti Jẹ́ Ìpè Ẹlẹdàá

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ́yọ́ nígbà kan rí, Ọ̀mọ̀wé Victor Ọmọlolú Olúnlọ́yọ̀ọ́ ti tẹ́rí gbasọ.Àná ní bàbá àgbà náà kú lẹ́yìn ọdún mọ́kàndínláàádọ́rùn-ún (89yrs) lókè eèpẹ̀.

Òun ni ó jẹ́ Gómìnà olóṣèlú kejì ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lẹ́yìn olóògbé Bọ́lá Ìgè.Ẹgbẹ́ Onílé NPN ló ló àtẹ̀gùn rẹ̀ láti jẹ Gómìnà ní ìgbà náà láàrin oṣù kẹwàá sí ìkejìlá ọdún 1983.

Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ìṣirò tí a mọ̀ sí Mathematics ní Ọ̀mọ̀wé Victor Ọmọlolú Olúnlọ́yọ̀ọ́, nínú rẹ náà ló sì ti gba oyè ọ̀mọ̀wé.

Òun ni ọ̀gá àgbà àkọ́kọ́ fún ilé ìwé Gbogbonìṣe ti a mọ̀ sí Polytechnic ti ilẹ̀ Ìbàdàn àti ti ìpínlẹ̀ Kwara.

Olúnlọ́yọ̀ọ́ ni Balógun ìlú Ọ̀yọ́ àti Bọ́bamẹ̀yẹí ti ìlú ilé-ifẹ̀ nígbà ayé rẹ̀.

Àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ wàá fi ògo fún Olórun fún ìgbé ayé rere tí bàbá náà gbé.Ìgbésẹ̀ láti ṣe ẹ̀yẹ ìkẹhìn fún olóògbé náà sì ti gbéra sọ.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×