
Àlùfáà àgbà ìjọ Great is the Lord Bible Church inc. tó wà ní ìlú Àkúrẹ́ ti rán gbogbo àwọn ènìyàn pàápàá jùlọ àwọn onígbàgbọ létí kí wọ́n rántí pé kò sí ẹni tó kọjá àdánwò.
Ìlú Àkúrẹ́ ló ti ṣe àlàyé ọ̀rọ̀ yìí nígbà tó ń wàásù lórí kókó ọ̀rọ̀ tó pè ní “Ìkápá ọ̀kanjúà ẹni:Má ṣe gba ẹran ara láàyè”nínú ilé ìjósìn náà láti fi ṣọrí ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọ̀kan pàtàkì nínú ọmọ ìjọ náà, Ọ̀gbẹ́ni Oluwaṣẹ́gun tó ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí àti ìrántí ìgbéyàwó wọn.
Jẹ́gẹ́dẹ́ kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Ọlọ́run láti ṣá fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ẹ́ yòówù tó le mú kí á jìnnà sí Ọlọ́run Jèhófà.Ó ní a kò lè wà nínú ẹ̀ṣẹ̀ ká pé kí a ní kí ore -ọ̀fẹ́ máa pò si
Nígbà tó ń gba ọlọ́jọ́ ìbí nímọ̀ràn,ó lu Ọ̀gbẹ́ni náà lọ́gọ ẹnu fún bí ó ti n ṣe ààtò ìdílé rẹ.Ó gbàdúrà kí Olúwa túbọ̀ mún ilé ró
Nígbà tó ń fèsì, Oluwasegun dupẹ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn pàápàá jùlọ Àlùfáà àti ìyàwó rè fún ìdodimú wọn.Bákan náà ló dupe lowo ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ tó péjú síbẹ̀.
Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn ló péjú síbẹ̀.Lara wọn ní Isaac Adébáyọ̀ tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Babalábúlé, Gómìnà ìpínlẹ̀ Oǹdó fún ẹgbẹ́ ANBROAD, àti igbákejî rẹ̀, Ọ̀gbẹ́ni Oyè Oyèdọ̀tun àti Sẹ́gun Ajíbólá àtàwọn ogunlọ́gọ̀ ènìyàn.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
