
Olórí àjọ Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ tí a mọ̀ sí DSS ní ilẹ̀ wa Naijiria,Olúwatóṣìn Àjàyí ti pè fún òfin tí yóò máa ṣe àtìlẹ́yìn fún àwọn ará ìlú láti máa dáàbò bo ara wọn lọ́wọ́ àwọn Aṣẹ̀rùbàlú, Ajínigbé,ìkọlù àwọn Fúlàní darandaran àti àwon ìpèníjà ètò àbò mìíràn.
Àjàyí fojú ọ̀rọ̀ yìí léde níbi ìpàdé awọn ẹni ọ̀rọ̀ kàn ní ìgbánnu ètò àbò tó wáyé lópin ọ̀ṣẹ̀ tó kọjá lọ.
Àjàyí ní iye àwọn ọlọ́pàá, ọmọ ogun àti àwọn òsìṣẹ́ ètò àbò tó wà ní ilẹ wa Nàìjíríà kéré púpọ̀ jù láti kojú ìpèníjà ètò àbò tí orílẹ̀-èdè yìí ń kojú.Fun ìdí èyí,ó yẹ kí àwọn ará ìlú máa le dáàbò bo ara wọn kí wọ́n má sì ṣe la ojú sílẹ̀ ki tàlùbọ̀ wọ̀ ọ́.Kò sí ohun tó burú nínú kí á máa dúró de elétò àbò tí wọ́n kò tó titi ti nǹkan yóò fi bàjẹ́.
Ó ṣe àpèjúwe ohun tó ṣẹlẹ̀ ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Tafawa Balewa ní ìpínlẹ̀ Bauchi ní ibi tí àwọn ará ìlú ti jáwé akìwọwọ fún àwọn Àṣẹ̀rùbàlú tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n lé wọn ti ẹsẹ̀ wọn kò balẹ̀.
Àjàyí ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà túmọ̀ sí wí pé bí ìjọba bá fún àwọn ènìyàn ní àtìlẹ́yìn,wọ́n tó ìjà ara wọn í gbè.Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ìjọba yèé lu ìlù máa jó lọ mò ń wò ẹ̀yìn rẹ fún àwọn ará ìlú nípa kí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àpapọ̀ ṣe òfin tí yóò ti èròngbà náà lẹ́yìn.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
