
Ilé-iṣẹ́ Atúnrinrọ ti ó wà ní ìlú Àjàòkúta ní ìpínlẹ̀ Kogi ni ó ti ní Adarí tuntun.Ẹnu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí ni Ààrẹ Bọ́lá Tinúbú yan ọkùnrin náà si ipò pàtàkì yìí.Ìyànsípò rẹ̀ sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe iṣẹ́ lójú ẹsẹ̀.
Onitọ̀hún ní Olùbádámọ̀ràn pàtàkì fún Mínísítà fún ètò agbára ní ilẹ̀ yìí.Òun yìí kan náà ni olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún ilé ìwé National Institute for Legal and Democratic study.Orúkọ rẹ̀ ní Ọ̀gbẹ́ni Abdulsalam.
Ààrẹ ilẹ̀ Nàìjíríà,Bọ́lá Tinúbú gbé ìgbésẹ̀ náà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà ìyannisípò òsèlú àti iṣẹ́ ọba, abala kejìdínlọ́gbọ̀n rẹ̀.
Ó wá rọ̀ ọ́ kó má ṣe já ilẹ̀ Nàìjíríà ní tànmọ́-ọ̀n kó sì ṣe iṣẹ́ tẹ̀lé ìpinnu ìjọba rẹ̀ láti mú ìrètí ọ̀tun ti yóò tún ilé-iṣẹ́ náà sọ bí ẹní ṣọ igbá bá ilé iṣẹ́ ọ̀hún.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
