Yekeen Adéọjọ, Àgbà Òṣèlú ní ilẹ̀ Ìbàdàn di Olóògbé

Alhaji Yekeen Adéọjọ

Èèkàn nínú olóṣèlú kan tó tí fìgbà kan rí díje fún ipò gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP , Alhaji Yekeen Adéọjọ ti di olóògbé.

Òwúrọ̀ àná ló jẹ́ ìpè Ẹlẹdàá.Títí di àsìkò tí a ń kó ìròyìn yìí jọ, àṣírí ikú tó pa àgbà òṣèlú náà kò tíì hàn sí wa.

Ọ̀kan lára àwọn ọmọ rẹ̀,Sherif Adéọjọ tíì tún ṣe alága ìjọba ìbílẹ̀ Ìdó ló fi ìròyìn náà léde.

Adéọjọ ló díje fún ipò gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ọdún 1999 ṣùgbọ́n tó fìdí rẹmi, tí ipò náà sì já mọ́ Olóògbé Lam Adéṣínà lọ́wọ́ .

Ajagunfẹ̀hìntì ní Yekeen Adéọjọ kó tó gbé igbá òsèlú.Ki Olúwa tẹ́ ẹ sí afẹ́fẹ́ rere

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×