Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ yọ Abure bíi alága ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party

Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní ilẹ̀ Nàìjíríà ti yọ Julius Abure gẹ́gẹ́ bíi alága àpapọ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party.

Òní ní ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ gbé ìdájọ́ rẹ̀ kálẹ̀ ní ìlú Abuja nípasẹ̀ ẹjọ́  tí Sẹ́nétọ̀ Esther Nenandi Usman pè tako ìdájọ ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tó ní kí Julius Abure máa bá iṣẹ rẹ̀ lọ gẹ́gẹ́ bíi alága ẹgbẹ́ òṣèlú náà . Ṣùgbọ́n ilé ẹjọ́ tó ga jù lọ tí da ìdájọ ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn nù, ó sì ti fi ọwọ́ òsi júwe ilé fún Abure

Ilé ẹjọ́ náà ní Abure ti lo sáà rẹ̀ tán gégé bíi alága , niwòn-igba-ti kò sí ìpàdé gbogbogbòò tó gúnmọ́ tó ṣe àtúnyàn ipò fún Abure ṣe ló yẹ kí ó gba ilé rẹ̀ lọ nígbà tí kìí ṣe oyè ìdílé.

Ní báyìí, tí òdodo ti fara hàn lórí ipò alága ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party, tí Igi ọ̀rọ̀ náà sì wó sí ìbi tí Peter Obi àti àwọn èèkàn ẹgbẹ́ mìíràn fẹ́ kó wó sí; ó ṣe í ṣe kí ẹgbẹ́ òṣèlú náà jí kúrò nínú oorun rẹ̀ pàápàá jùlọ bí ìpalẹ̀mọ́ fún ìdìbò ọdún 2027 ti ń fojoojúmọ́ súnmọ́

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×