
Ẹgbẹ́ Akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí a mọ̀ sí ANBROAD , ẹ̀ka ti ìpínlẹ̀ Oǹdó ti kí igbákejì Gómìnà ìpínlẹ̀ Oǹdó, Ọ̀gbẹ́ni Ọláyídé Adélàmí kú oríire ayéyẹ ọjọ ìbí rẹ̀ tó tún kò.
Àtẹ̀jáde kan tó jáde nípasẹ̀ alukoro ẹgbẹ́ náà, Ọ̀gbẹ́ni Adékúnlé Adéwùmí ti àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ mọ̀ sí Kẹ̀kẹ́ Àwàdà ṣe àpèjúwe igbákejì gómìnà bíi olóòótọ ẹ̀dá, ẹni tó ṣe é fọkàn tán àti olólùfẹ́ Mèkúnnù tó ti kó ipa ribiribi láti mú ìlọsíwájú bá àwùjọ rẹ̀,gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ ọba àtí bíi olóṣèlú.
Ẹgbẹ́ Akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ ANBROAD wá ṣe ádùrá pé pípẹ́ lowú ń ṣe ilé arọ́,ògbókàngiri là ń bá ẹdan ní ilédì.Ki Adélàmí dàgbà bí ará àárọ̀.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
