
Mínísítà fún olú ìlú ilẹ̀ wa, Nyensom Wike ti fèsì sí ọ̀rọ̀ kan tó ń jà ràn-ìn-ràn-ìn kiri pé ara rẹ̀ kò yá àti pé ó subú lulẹ̀ nílé ìjọba wọ́n sì ti gbé e lọ sí orílẹ̀-èdè Faransé fún ìtọ́jú tó péye.
Wike ni bíi kó kú,kó kú;ni ewúrẹ́ ń wo alápatà .Bẹ́ẹ̀ sì rèé, bí òun kò bá kú lógún ọdún,baba ẹnìkan kò lè gbé òun ṣin.Ó wá ṣe àpèjúwe ọ̀rọ̀ náà bíi ọ̀rọ̀ òsèlú tí kò ní ẹsẹ̀ nílẹ̀ rárá.
Mínísítà fún olú ìlú ilẹ̀ wa tẹ̀ síwájú pé ọ̀dọ̀ Ààrẹ Tinúbú ni òun wà tí òun ti ń bá a sínu àwẹ̀ lọ́jọ́ ti ọ̀rọ̀ burúkú òhun yọjú sí ìgboro.Ọjọ́ kejì sì ni òun kó àwọn ènìyàn àti olùgbé olú ìlú ilẹ̀ wa ṣòdí láti lọ kí Ààrẹ fún ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀.
Ó ní ‘Sé ẹ ṣáà rí mi pé kó sí ohun tó ṣe mí.Àwọn tí wọ́n ń gbé sùnmọ̀mí kiri ni nǹkan ń ṣe.Ọ̀rọ̀ Òṣèlú ni wọ́n fi ṣe,omi tí a bá sì fi ṣe ẹyin adìrẹ kìí mọ́ ọn lára, èmi ni n ó jẹ àkàrà àwọn ọ̀tá mi .’ Gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers àná sọ síwájú pé kò sí ẹni tí yóò ju ṣáyé.Bí a fẹ́, bí a kò, gbogbo wa la ó lọ ní ọjọ́ kan.Ó wá ní kí àwọn ọmọ Naijiria ka ọ̀rọ̀ náà kún igbe ọ̀wàwà nítori ọ̀rọ̀ játijàti ni.
Wike ṣe àlàyé àwọn ọ̀rọ̀ yìí nígbà tó ń ṣe àyẹ̀wò àwọn iṣẹ́ àkànṣe bíi mélòó kan yíká ìlú Abuja .Gẹ́gẹ́ bó ṣe wí, àwọn òkan-o-jòkan àkànṣe iṣẹ́ náà yóò ti wà nílẹ̀ fún síṣí lásìkò tí Ààrẹ bá ń ṣe ayẹyẹ ọdún Kejì lórí àléfà.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
